Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 13:6 - Yoruba Bible

6 Ó wá pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Ẹnìkan gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ sinu ọgbà rẹ̀. Ó dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, ṣugbọn kò rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 O si pa owe yi fun wọn pe: Ọkunrin kan ni igi ọpọtọ kan ti a gbìn si ọgbà ajara rẹ̀; o si de, o nwá eso lori rẹ̀, kò si ri nkan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Ó sì pa òwe yìí fún wọn pé: “Ọkùnrin kan ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí a gbìn sí ọgbà àjàrà rẹ̀; ó sì dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, kò sì rí nǹkan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 13:6
14 Iomraidhean Croise  

Sibẹ mo gbìn yín gẹ́gẹ́ bí àjàrà tí mo fẹ́, tí èso rẹ̀ dára. Báwo ni ẹ ṣe wá yipada patapata, tí ẹ di àjàrà igbó tí kò wúlò?


“Ní àkókò ìkórè, kò ní sí èso lórí àjàrà, igi ọ̀pọ̀tọ́ kò ní ní èso lórí, àwọn ewé pàápàá yóo gbẹ, ohun tí mo fún wọn yóo di ti ẹlòmíràn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


Rárá ó! Mo sọ fun yín pé bí ẹ kò bá ronupiwada, gbogbo yín ni ẹ óo ṣègbé bákan náà.”


A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí. Nítorí náà, igikígi tí kò bá máa so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná.”


Kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ yàn mí. Èmi ni mo yàn yín, tí mo ran yín pé kí ẹ lọ máa so èso tí kò ní bàjẹ́, kí Baba lè fun yín ní ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi.


Ṣugbọn èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, alaafia, sùúrù, àánú, iṣẹ́ rere, ìṣòtítọ́,


Kì í ṣe ẹ̀bùn ni mò ń wá, ṣugbọn mò ń wá ọpọlọpọ èso fún anfaani yín.


Ṣugbọn igi ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí n pa èso mi dáradára tí ó ládùn tì, kí n wá jọba lórí yín?’


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan