Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 12:5 - Yoruba Bible

5 N óo fi ẹni tí ẹ̀ bá bẹ̀rù hàn yín. Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó jẹ́ pé nígbà tí ó bá pa ara tán, ó ní àṣẹ láti tún sọ eniyan sinu ọ̀run àpáàdì. Mo sọ fun yín, ẹ bẹ̀rù olúwarẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ṣugbọn emi o si sọ ẹniti ẹnyin o bẹ̀ru fun nyin: Ẹ bẹru ẹniti o lagbara lẹhin ti o ba pani tan, lati wọ́ni lọ si ọrun apadi; lõtọ ni mo wi fun nyin, On ni ki ẹ bẹru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpáàdì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 12:5
16 Iomraidhean Croise  

Àwọn eniyan burúkú, àní, gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọrun, ni yóo lọ sinu isà òkú.


Ninu ìbẹ̀rù OLUWA ni igbẹkẹle tí ó dájú wà, níbẹ̀ ni ààbò wà fún àwọn ọmọ ẹni.


Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè? Nítorí ẹ̀tọ́ rẹ ni; kò sì sí ẹni tí ó gbọ́n tó ọ láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè, ati ni gbogbo ìjọba wọn.


nítorí pé Iṣimaeli ọmọ Netanaya ti pa Gedalaya, ọmọ Ahikamu, tí ọba Babiloni fi ṣe gomina ilẹ̀ náà.


Ẹ̀rù mi kò tilẹ̀ bà yín? Èmi OLUWA ni mò ń bi yín léèrè. Ẹ wà níwájú mi ẹ kò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Èmi tí mo fi iyanrìn pààlà fún omi òkun, tí òkun kò sì gbọdọ̀ rékọjá rẹ̀ títí ayé! Bí ó tilẹ̀ ń ru sókè, kò lágbára kan, kí ìgbì rẹ̀ máa hó yaya, kò lè kọjá ààlà náà.


Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara yín, tí wọn kò lè pa ẹ̀mí yín. Ẹni tí ó yẹ kí ẹ bẹ̀rù ni Ọlọrun tí ó lè pa ẹ̀mí ati ara run ní ọ̀run àpáàdì.


“Nígbà náà ni yóo wá sọ fún àwọn tí ó wà ní ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún. Ẹ lọ sinu iná àjóòkú tí a ti pèsè sílẹ̀ fún èṣù ati àwọn angẹli rẹ̀.


Àwọn wọnyi ni yóo lọ sinu ìyà àìlópin. Ṣugbọn àwọn olódodo yóo wọ ìyè ainipẹkun.”


Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹni tí ó bá bínú sí arakunrin rẹ̀ yóo bọ́ sinu ẹjọ́. Ẹni tí ó bá bú arakunrin rẹ̀, yóo jẹ́jọ́ níwájú àwọn ìgbìmọ̀ ìlú. Ẹni tí ó bá sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ìwọ òmùgọ̀ yìí’ yóo wà ninu ewu iná ọ̀run àpáàdì.


Ṣugbọn ẹ̀yin, ní tiyín, ẹ ṣọ́ra. Mo ti sọ ohun gbogbo fun yín tẹ́lẹ̀.


Èyí kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ojú tẹmbẹlu arakunrin rẹ̀, tabi kí ó ṣẹ arakunrin rẹ̀ nípa ọ̀ràn yìí. Nítorí ẹlẹ́san ni Oluwa ninu àwọn ọ̀ràn wọnyi, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, tí a wá tún ń kìlọ̀ fun yín nisinsinyii.


Ohun tí ó bani lẹ́rù gidigidi ni pé kí ọwọ́ Ọlọrun alààyè tẹ eniyan.


Nítorí Ọlọrun kò dáríjì àwọn angẹli tí ó ṣẹ̀ ẹ́, ṣugbọn ó jù wọ́n sinu ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri ní ọ̀run àpáàdì títí di ọjọ́ ìdájọ́.


Ó bá kígbe pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí àkókò ìdájọ́ rẹ̀ dé! Ẹ júbà ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, òkun ati gbogbo orísun omi.”


Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, Oluwa? Ta ni kò ní fi ògo fún orúkọ rẹ? Nítorí ìwọ nìkan ni ó pé, nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo júbà níwájú rẹ, nítorí òdodo rẹ farahàn gbangba.”


Ni a bá ju ikú ati ipò òkú sinu adágún iná. Adágún iná yìí ni ikú keji.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan