Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 12:4 - Yoruba Bible

4 “Mò ń sọ fun yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, pé kí ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara, tí kò tún sí ohun tí wọ́n le ṣe mọ́ lẹ́yìn rẹ̀!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Emi si wi fun nyin ẹnyin ọrẹ́ mi, Ẹ máṣe bẹ̀ru awọn ti ipa ara enia kú, lẹhin eyini ti nwọn kò si li eyiti nwọn le ṣe mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 “Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 12:4
20 Iomraidhean Croise  

Ìbẹ̀rù eniyan a máa di ìdẹkùn fún eniyan, ṣugbọn ẹni bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo wà láìléwu.


Mo wọ inú ọgbà mi, arabinrin mi, iyawo mi. Mo kó òjíá ati àwọn turari olóòórùn dídùn mi jọ, mo jẹ afárá oyin mi, pẹlu oyin inú rẹ̀, mo mu waini mi ati wàrà mi. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ jẹ, kí ẹ sì mu, ẹ mu àmutẹ́rùn, ẹ̀yin olùfẹ́.


Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn, àfi bí oyin, ó wuni lọpọlọpọ. Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, òun ni olùfẹ́ mi, òun sì ni ọ̀rẹ́ mi,


“Ìwọ ní tìrẹ, Israẹli iranṣẹ mi, Jakọbu, ìwọ tí mo ti yàn, ọmọ bíbí inú Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi.


Ṣugbọn, ìwọ dìde, di àmùrè rẹ, kí o sì sọ gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ fún wọn. Má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn ó bà ọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo dẹ́rù bà ọ́ níwájú wọn.


Má bẹ̀rù wọn, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo sì gbà ọ́.”


nítorí pé Iṣimaeli ọmọ Netanaya ti pa Gedalaya, ọmọ Ahikamu, tí ọba Babiloni fi ṣe gomina ilẹ̀ náà.


“Ṣugbọn ìwọ ọmọ eniyan, má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà ọ́, má sì bẹ̀rù ọ̀rọ̀ tí wọn ń sọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀gún ọ̀gàn ati ẹ̀wọ̀n agogo yí ọ ká, tí o sì jókòó láàrin àwọn àkeekèé, má ṣe bẹ̀rù ohunkohun tí wọn bá wí. Má jẹ́ kí ojú wọn dẹ́rù bà ọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.


Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara yín, tí wọn kò lè pa ẹ̀mí yín. Ẹni tí ó yẹ kí ẹ bẹ̀rù ni Ọlọrun tí ó lè pa ẹ̀mí ati ara run ní ọ̀run àpáàdì.


Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó ju èyí lọ, pé ẹnìkan kú nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.


Ṣugbọn n kò ka ẹ̀mí mi sí ohunkohun tí ó ní iye lórí fún ara mi. Ohun tí mò ń lépa ni láti parí iré ìje mi ati iṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Oluwa mi Jesu, èyí ni pé kí n tẹnu mọ́ ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.


Nígbà tí wọ́n rí ìgboyà Peteru ati ti Johanu, tí wọ́n wòye pé wọn kò mọ ìwé àtipé òpè eniyan ni wọ́n, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ṣe akiyesi wọn pé wọ́n ti wà pẹlu Jesu.


Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù àwọn alátakò bà yín rárá ninu ohunkohun. Èyí ni yóo jẹ́ ẹ̀rí ìparun wọn, yóo sì jẹ́ ẹ̀rí ìgbàlà yín. Ọlọrun ni yóo ṣe é.


Èyí ni ó mú kí Ìwé Mímọ́ ṣẹ tí ó sọ pé, “Abrahamu gba Ọlọrun gbọ́, Ọlọrun sì kà á sí olódodo.” A wá pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọrun.


Ṣugbọn bí ẹ bá tilẹ̀ jìyà nítorí òdodo, ẹ ṣe oríire. Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọn ń jẹ yín níyà, kí ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín dàrú.


Má bẹ̀rù ohunkohun tí ò ń bọ̀ wá jìyà. Èṣù yóo gbé ẹlòmíràn ninu yín jù sinu ẹ̀wọ̀n láti fi dán yín wò. Fún ọjọ́ mẹ́wàá ẹ óo ní ìṣòro pupọ. Ṣugbọn jẹ́ olóòótọ́ dé ojú ikú, Èmi yóo sì fún ọ ní adé ìyè.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan