Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 12:2 - Yoruba Bible

2 Ṣugbọn kò sí ohun kan tí a fi aṣọ bò tí a kò ní ṣí aṣọ lórí rẹ̀. Kò sì sí ohun àṣírí tí eniyan kò ní mọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Kò si ohun ti a bò, ti a kì yio si fihàn; tabi ti o pamọ, ti a ki yio mọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 12:2
10 Iomraidhean Croise  

Nítorí Ọlọrun yóo mú gbogbo nǹkan tí eniyan bá ṣe wá sí ìdájọ́, ati gbogbo nǹkan àṣírí, ìbáà ṣe rere tabi burúkú.


Nítorí pé mò ń wo gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, kò sí èyí tí n kò rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò sápamọ́ fún mi.


Wọ́n fẹ́ràn ati máa rúbọ; wọ́n ń fi ẹran rúbọ, wọ́n sì ń jẹ ẹ́; ṣugbọn inú OLUWA kò dùn sí wọn. Yóo wá ranti àìdára wọn nisinsinyii, yóo sì jẹ wọ́n níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn; wọn óo sì pada sí Ijipti.


Nítorí kò sí ohun tí a fi pamọ́ tí a kò ní gbé jáde, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun ìkọ̀kọ̀ kan tí a kò ní yọ sí gbangba.


“Nítorí kò sí ohun kan tí ó pamọ́ tí kò ní fara hàn, kò sì sí nǹkan bòńkẹ́lẹ́ kan tí eniyan kò ní mọ̀.


ní ọjọ́ tí Ọlọrun yóo rán Jesu láti ṣe ìdájọ́ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo tí ó wà ninu eniyan gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí mò ń waasu.


Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìdájọ́ kí àkókò rẹ̀ tó tó, nígbà tí Oluwa yóo dé, tí yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ohun gbogbo tí ó fara pamọ́ sinu òkùnkùn, tí yóo mú kí gbogbo èrò ọkàn eniyan farahàn kedere. Nígbà náà ni olukuluku yóo gba iyìn tí ó yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.


Nítorí gbogbo wa níláti lọ siwaju Kristi bí a ti rí, láti lọ jẹ́ ẹjọ́. Níbẹ̀ ni olukuluku yóo ti gba ohun tí ó tọ́ sí i fún oríṣìíríṣìí ìwà tí ó ti hù nígbà tí ó wà ninu ara, ìbáà ṣe rere, ìbáà ṣe burúkú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan