Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 12:1 - Yoruba Bible

1 Ní àkókò yìí, ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ; wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn fi ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀. Jesu kọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ná. Ó ní, “Ẹ ṣọ́ ara yín nípa ìwúkàrà àwọn Farisi, àwọn alágàbàgebè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O si ṣe, nigbati ainiye ijọ enia pejọ pọ̀, tobẹ̃ ti nwọn ntẹ̀ ara wọn mọlẹ, o tètekọ́ wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ mã ṣọra nyin nitori iwukara awọn Farisi, ti iṣe agabagebe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ó sì ṣe, nígbà tí àìníye ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sísọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa ṣọ́ra yín nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi tí í ṣe àgàbàgebè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 12:1
18 Iomraidhean Croise  

Ọba Israẹli fi ìtọ́jú ẹnubodè ìlú sí abẹ́ àkóso ọ̀gágun tí ó jẹ́ aṣojú rẹ̀. Àwọn eniyan sì tẹ ọ̀gágun náà pa, gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọtẹ́lẹ̀ nígbà tí ọba lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.


pé bí inú eniyan burúkú bá ń dùn, tí ẹni tí kò mọ Ọlọrun bá ń yọ̀, fún ìgbà díẹ̀ ni.


Ìrètí wo ni ẹni tí kò mọ Ọlọrun ní nígbà tí Ọlọrun bá pa á run, tí Ọlọrun sì gba ẹ̀mí rẹ̀?


“Àwọn tí kò mọ Ọlọrun fẹ́ràn ibinu, wọn kì í kígbe fún ìrànlọ́wọ́, nígbà tí ó bá fi wọ́n sinu ìdè.


Ẹ̀rù ń ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó wà ní Sioni; ìjayà mú àwọn ẹni tí kò mọ Ọlọrun. Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná ajónirun? Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná àjóòkú?


Ẹ gbé! Nítorí ẹ dàbí ibojì tí kò ní àmì, tí àwọn eniyan ń rìn lórí wọn, tí wọn kò mọ̀.”


Ẹ̀yin alágàbàgebè! Ẹ mọ àmì ilẹ̀ ati ti ojú sánmà, ṣugbọn ẹ kò mọ àmì àkókò yìí!


Ní àkókò kan, bí Jesu ti dúró létí òkun Genesarẹti, ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.


Ṣugbọn ńṣe ni ìròyìn rẹ̀ túbọ̀ ń tàn kálẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan wá ń péjọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ati kí ó lè wò wọ́n sàn kúrò ninu àìlera wọn.


Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu wọn, ó dúró ní ibi tí ilẹ̀ gbé tẹ́jú. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti gbogbo Judia ati Jerusalẹmu ati Tire ati Sidoni, ní agbègbè ẹ̀bá òkun.


Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun. Àwọn náà wá sọ fún un pé, “Wò ó ná, arakunrin, ṣé o mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn Juu tí ó gba Jesu gbọ́, tí gbogbo wọn sì ní ìtara sí Òfin Mose.


Nítorí ohun kinni tí ó ṣe pataki jùlọ tí èmi fúnra mi kọ́, tí mo sì fi kọ́ yín ni pé Kristi kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.


Ṣugbọn òkè Sioni ni ẹ wá, ìlú Ọlọrun alààyè, Jerusalẹmu ti ọ̀run, pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹrun angẹli. Ẹ wá sí àjọyọ̀ ogunlọ́gọ̀ eniyan,


Ṣugbọn ní àkọ́kọ́, ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ pípé, lẹ́yìn náà a máa mú alaafia wá, a máa ṣe ẹ̀tọ́, a máa ro ọ̀rọ̀ dáradára, a máa ṣàánú; a máa so èso rere, kì í ṣe ẹnu meji, kì í ṣe àgàbàgebè.


Nítorí náà, ẹ pa gbogbo ìwà ibi tì, ati ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, àgàbàgebè, owú jíjẹ ati ọ̀rọ̀ àbùkù.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan