Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 11:4 - Yoruba Bible

4 Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa náà ń dáríjì gbogbo ẹni tí ó bá jẹ wá ní gbèsè. Má ṣe fà wá sinu ìdánwò.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ki o si dari ẹ̀ṣẹ wa jì wa; nitori awa tikarawa pẹlu a ma darijì olukuluku ẹniti o jẹ wa ni gbese. Má si fà wa sinu idẹwò; ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá; nítorí àwa tìkára wa pẹ̀lú a máa dáríjì olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè, Má sì fà wá sínú ìdánwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni búburú ni.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 11:4
31 Iomraidhean Croise  

kí angẹli tí ó yọ mí ninu gbogbo ewu bukun wọn; kí ìrántí orúkọ mi, ati ti Abrahamu, ati ti Isaaki, àwọn baba mi, wà ní ìran wọn títí ayé, kí atọmọdọmọ wọn pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.”


gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, kí o sì mú wọn pada wá sórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn.


gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji Israẹli, iranṣẹ rẹ, àní, àwọn eniyan rẹ, kí o sì kọ́ wọn ní ọ̀nà rere tí wọn yóo máa tọ̀; lẹ́yìn náà, rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ tí o fi fún àwọn eniyan rẹ bí ohun ìní.


OLUWA óo dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ gbogbo ibi, yóo pa ọ́ mọ́.


Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí mo jẹ̀bi lọpọlọpọ.


Wo ìpọ́njú ati ìdààmú mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.


Gbọ́ tiwa, OLUWA, dáríjì wá, tẹ́tí sí wa, OLUWA, wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí, má sì jẹ́ kí ó pẹ́, nítorí orúkọ rẹ, tí a fi ń pe ìlú rẹ ati àwọn eniyan rẹ.”


Ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, kí ẹ sọ pé, “Mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, gba ohun tí ó dára a óo sì máa yìn ọ́ lógo.


“Bẹ́ẹ̀ ni Baba mi ọ̀run yóo ṣe si yín bí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín kò bá fi tọkàntọkàn dáríjì arakunrin rẹ̀.”


Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò. Ẹ̀mí fẹ́ ṣe é, ṣugbọn ara kò lágbára.”


Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Bí ẹnìkan ninu yín bá ní ọ̀rẹ́ kan, tí ó wá lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ yìí ní ọ̀gànjọ́ òru, tí ó sọ fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́ mi, yá mi ní burẹdi mẹta,


Tabi àwọn mejidinlogun tí ilé-ìṣọ́ gíga ní Siloamu wólù, tí ó pa wọ́n, ṣé ẹ rò pé wọ́n burú ju gbogbo àwọn eniyan yòókù tí ó ń gbé Jerusalẹmu lọ ni?


Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀ ń sùn ni! Ẹ dìde kí ẹ máa gbadura, kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdánwò.”


Àwọn tí ó bọ́ sórí òkúta ni àwọn tí ó gbọ́, tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, ṣugbọn wọn kò ní gbòǹgbò. Wọ́n gbàgbọ́ fún àkókò díẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ìdánwò dé, wọ́n bọ́hùn.


N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o mú wọn kúrò ninu ayé. Ẹ̀bẹ̀ mi ni pé kí o pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ Èṣù.


Kò sí ìdánwò kan tí ó dé ba yín bíkòṣe irú èyí tí ó wọ́pọ̀ láàrin eniyan. Ṣugbọn Ọlọrun tó gbẹ́kẹ̀lé, kò ní jẹ́ kí ẹ rí ìdánwò tí ó ju èyí tí ẹ lè fara dà lọ. Ṣugbọn ní àkókò ìdánwò, yóo pèsè ọ̀nà àbáyọ, yóo sì mú kí ẹ lè fara dà á.


Ẹ ní ìfaradà láàrin ara yín. Ẹ máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnìkejì rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti dáríjì yín bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí ara yín.


Ṣugbọn olódodo ni Oluwa, òun ni yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóo sì pa yín mọ́ kúrò ninu ibi gbogbo.


Oluwa yóo yọ mí kúrò ninu iṣẹ́ burúkú gbogbo, yóo sì gbà mí sinu ìjọba rẹ̀ ní ọ̀run. Tirẹ̀ ni ògo lae ati laelae. Amin.


Nítorí kò ní sí àánú ninu ìdájọ́ fún àwọn tí kò ní ojú àánú, bẹ́ẹ̀ sì ni àánú ló borí ìdájọ́.


Má bẹ̀rù ohunkohun tí ò ń bọ̀ wá jìyà. Èṣù yóo gbé ẹlòmíràn ninu yín jù sinu ẹ̀wọ̀n láti fi dán yín wò. Fún ọjọ́ mẹ́wàá ẹ óo ní ìṣòro pupọ. Ṣugbọn jẹ́ olóòótọ́ dé ojú ikú, Èmi yóo sì fún ọ ní adé ìyè.


Nítorí o ti fi ìfaradà pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Èmi náà yóo pa ọ́ mọ́ ní àkókò ìdánwò tí ń bọ̀ wá bá ayé, nígbà tí a óo dán gbogbo àwọn tí ó ń gbé inú ayé wò.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan