3 Máa fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lojoojumọ.
3 Fun wa li onjẹ ojọ wa li ojojumọ́.
3 Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lójoojúmọ́.
Jẹ́ kí ìwà èké ati irọ́ pípa jìnnà sí mi, má jẹ́ kí n talaka, má sì jẹ́ kí n di ọlọ́rọ̀, fún mi ní ìwọ̀nba oúnjẹ tí ó tó mi jẹ,
Ibi ààbò ni yóo máa gbé, àpáta ńlá ni yóo jẹ́ ibi ààbò rẹ̀. Yóo máa rí oúnjẹ jẹ déédé, yóo sì máa rí omi mu lásìkò, lásìkò.
Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí.
Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn nípa nǹkan ti ọ̀la; nítorí ọ̀la ni nǹkan ti ọ̀la wà fún; wahala ti òní nìkan ti tó fún òní láì fi ti ọ̀la kún un.
Àwọn yìí ṣe onínú rere ju àwọn Juu ti Tẹsalonika lọ. Wọ́n fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Lojoojumọ ni wọ́n ń wá inú Ìwé Mímọ́ wò láti rí bí àwọn ohun tí wọ́n kọ́ wọn rí bẹ́ẹ̀.