Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 10:8 - Yoruba Bible

8 Ìlúkílùú tí ẹ bá wọ̀, tí wọn bá gbà yín, ẹ máa jẹ ohun tí wọn bá gbé kalẹ̀ níwájú yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Ati ni ilukilu ti ẹnyin ba wọ̀, ti nwọn ba si gbà nyin, ẹ jẹ ohunkohun ti a ba gbé kà iwaju nyin:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 “Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 10:8
6 Iomraidhean Croise  

“Ẹni tí ó bá gbà yín, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi.


Ṣugbọn ìlúkílùú tí ẹ bá wọ̀ tí wọn kò bá gbà yín, ẹ jáde lọ sí títì ibẹ̀, kí ẹ sọ pé,


Ó wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọde yìí ní orúkọ mi, èmi ni ó gbà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi. Nítorí ẹni tí ó kéré jùlọ ninu yín, òun ló jẹ́ eniyan pataki jùlọ.”


Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.”


Bí ẹnìkan ninu àwọn alaigbagbọ bá pè yín wá jẹun, tí ẹ bá gbà láti lọ, ẹ jẹ ohunkohun tí ó bá gbé kalẹ̀ níwájú yín láì wádìí ohunkohun, kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́.


Bẹ́ẹ̀ gan-an ni Oluwa pàṣẹ pé kí àwọn tí ó ń waasu ìyìn rere máa jẹ láti inú iṣẹ́ ìyìn rere.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan