Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 10:7 - Yoruba Bible

7 Ninu ilé kan náà ni kí ẹ máa gbé. Ohun tí wọ́n bá gbé kalẹ̀ fun yín ni kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu. Owó iṣẹ́ alágbàṣe tọ́ sí i. Ẹ má máa lọ láti ilé dé ilé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ni ile kanna ni ki ẹnyin ki o si gbé, ki ẹ mã jẹ, ki ẹ si mã mu ohunkohun ti nwọn ba fifun nyin; nitori ọ̀ya alagbaṣe tọ́ si i. Ẹ maṣe ṣi lati ile de ile.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ẹ dúró sínú ilé náà, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fi fún yín; nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i, Ẹ má ṣe lọ láti ilé dé ilé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 10:7
18 Iomraidhean Croise  

Ẹ̀yin ati ẹbí yín lè jẹ ìyókù níbikíbi tí ẹ bá fẹ́, nítorí pé ó jẹ́ èrè yín fún iṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe ninu Àgọ́ Àjọ.


Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Ilékílé tí ẹ bá wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò ní ìlú náà.


Bí ọmọ alaafia bá wà níbẹ̀, alaafia yín yóo máa wà níbẹ̀. Bí kò bá sí, alaafia yín yóo pada sọ́dọ̀ yín.


Ilé tí ẹ bá wọ̀ sí, níbẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò ní ìlú náà.


Òun ati àwọn ará ilé rẹ̀ gba ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀ wá pé, bí a bá gbà pé òun jẹ́ onigbagbọ nítòótọ́, kí á máa bọ̀ ní ilé òun kí á máa bá àwọn gbé. Ó tẹnu mọ́ ọn títí a fi gbà.


Ó bá mú wọn wọ ilé, ó fún wọn ní oúnjẹ. Inú òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ dùn pupọ nítorí ó ti gba Ọlọrun gbọ́.


Nígbà tí wọ́n jáde kúrò lẹ́wọ̀n, wọ́n lọ sí ilé Lidia. Lẹ́yìn tí wọ́n rí àwọn onigbagbọ, tí wọ́n sì gbà wọ́n níyànjú, wọ́n kúrò níbẹ̀.


Ẹni tí ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ ìyìn rere gbọdọ̀ máa pín olùkọ́ rẹ̀ ninu àwọn nǹkan rere rẹ̀.


Ẹ óo sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ati ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin yín, ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà láàrin ìlú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín ninu ilẹ̀ yín.


Bákan náà ni wọn yóo jọ pín oúnjẹ wọn láìka ohun tí àwọn ará ilé rẹ̀ bá fi ranṣẹ sí i gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó kàn án ninu ogún baba rẹ̀ tí wọ́n tà.


Ati pé nígbà tí wọn bá ń tọ ojúlé kiri, wọ́n ń kọ́ láti ṣe ìmẹ́lẹ́. Kì í sì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nìkan, wọn a máa di olófòófó ati alátojúbọ̀ ọ̀ràn-ọlọ́ràn, wọn a sì máa sọ ohun tí kò yẹ.


Àgbẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ lóko ni ó kọ́ ní ẹ̀tọ́ sí ìkórè oko.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan