Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 10:4 - Yoruba Bible

4 Ẹ má mú àpò owó lọ́wọ́, tabi àpò báárà. Ẹ má wọ bàtà. Bẹ́ẹ̀ ní kí ẹ má kí ẹnikẹ́ni ní ọ̀nà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ẹ máṣe mu asuwọn, ẹ máṣe mu apò, tabi bàta: ẹ má si ṣe kí ẹnikẹni li ọ̀na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 10:4
13 Iomraidhean Croise  

Wọ́n gbé oúnjẹ wá fún un pé kí ó jẹ, ṣugbọn ó wí pé, “N kò ní jẹun títí n óo fi jíṣẹ́ tí wọ́n rán mi.” Labani dáhùn, ó ní, “À ń gbọ́.”


Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má wulẹ̀ dá mi dúró mọ́, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ṣe ọ̀nà mi ní rere, ẹ jẹ́ kí n lọ bá oluwa mi.”


Lẹ́yìn tí wọ́n ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ní gàárì tán, ó sọ fún iranṣẹ náà pé, “Jẹ́ kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà máa sáré dáradára, kí ó má sì dẹ̀rìn, àfi bí mo bá sọ pé kí ó má sáré mọ́.”


Eliṣa bá sọ fún Gehasi pé, “Ṣe gírí, kí o mú ọ̀pá mi lọ́wọ́, kí o sì máa lọ. Bí o bá pàdé ẹnikẹ́ni lọ́nà, má ṣe kí i, bí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má dáhùn.”


Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán, kí o sì kọjú sí ibi tí ò ń lọ tààrà.


Ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila, ó rán wọn lọ ní meji-meji, ó fi àṣẹ fún wọn lórí àwọn ẹ̀mí èṣù.


Ó wá sọ fún wọn pé, “Nígbà tí mo ran yín níṣẹ́ tí mo sọ fun yín pé kí ẹ má mú àpò owó ati igbá báárà lọ́wọ́, ati pé kí ẹ má wọ bàtà, kí ni ohun tí ẹ ṣe aláìní?” Wọ́n dáhùn pé, “Kò sí!”


Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki pé, “Ǹjẹ́ o ní ọ̀kọ̀ tabi idà kí o fún mi? Ìkánjú tí mo fi kúrò nílé kò jẹ́ kí n ranti mú idà tabi ohun ìjà kankan lọ́wọ́.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan