Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 10:1 - Yoruba Bible

1 Lẹ́yìn èyí, Oluwa yan àwọn mejilelaadọrin mìíràn, ó rán wọn ní meji-meji ṣiwaju rẹ̀ lọ sí gbogbo ìlú ati ibi tí òun náà fẹ́ dé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 LẸHIN nkan wọnyi, Oluwa si yàn adọrin ọmọ-ẹhin miran pẹlu, o si rán wọn ni mejimeji lọ ṣaju rẹ̀, si gbogbo ilu ati ibi ti on tikararẹ̀ yio gbé de.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 10:1
14 Iomraidhean Croise  

Mo sì rí aadọrin ninu àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dúró níwájú àwọn oriṣa wọnyi, Jaasanaya ọmọ Ṣafani dúró láàrin wọn. Olukuluku mú ohun tí ó fi ń sun turari lọ́wọ́, èéfín turari sì ń fẹ́ lọ sókè.


OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Yan aadọrin ninu àwọn àgbààgbà Israẹli, àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli mọ̀ ní olórí, kí o sì mú wọn wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kí wọ́n dúró pẹlu rẹ níbẹ̀.


Òun ni yóo ṣáájú Oluwa pẹlu ẹ̀mí Elija ati agbára rẹ̀. Yóo mú kí àwọn baba wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu àwọn ọmọ wọn. Yóo yí àwọn alágídí ọkàn pada sí ọ̀nà rere. Yóo sọ àwọn eniyan di yíyẹ lọ́dọ̀ Oluwa.”


“Ìwọ, ọmọ mi, wolii Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè ọ́, nítorí ìwọ ni yóo ṣáájú Oluwa láti palẹ̀ mọ́ dè é,


Nígbà tí Oluwa rí obinrin náà, àánú rẹ̀ ṣe é. Ó sọ fún un pé, “Má sunkún mọ́.”


ó rán wọn sí Oluwa láti bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?”


Ó bá rán àwọn oníṣẹ́ ṣiwaju rẹ̀. Wọ́n bá wọ inú ìletò àwọn ará Samaria kan láti ṣe ètò sílẹ̀ dè é.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan