Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 1:8 - Yoruba Bible

8 Nígbà tí ó yá, ó kan ìpín àwọn Sakaraya láti wá ṣe iṣẹ́ alufaa níwájú Ọlọrun ninu Tẹmpili.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 O si ṣe, nigbati o nṣe iṣẹ alufa niwaju Ọlọrun ni ipa iṣẹ́ tirẹ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Ó sì ṣe, nígbà tí ó ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà níwájú Ọlọ́run ni àkókò tirẹ̀

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 1:8
16 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n óo ṣe tẹ̀léra wọn níbi iṣẹ́ ṣíṣe ninu ilé OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Aaroni, baba wọn, ti là sílẹ̀ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun pa fún Israẹli.


Nadabu ati Abihu kú ṣáájú baba wọn láì bí ọmọ kankan. Nítorí náà, Eleasari, ati Itamari di alufaa.


Àwọn ọmọ Lefi fi ilẹ̀ wọn sílẹ̀ ati ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n kó wá sí Juda, ati Jerusalẹmu; nítorí pé Jeroboamu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lé wọn jáde, wọn kò jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí alufaa Ọlọrun.


Ninu àwọn alufaa tí wọ́n wà ní ìlú àwọn ìran Aaroni ní ilẹ̀ gbogbogbòò ati ninu ìletò wọn, ni àwọn olóòótọ́ wà, tí wọ́n yàn láti máa pín oúnjẹ fún olukuluku ninu àwọn alufaa ati àwọn tí orúkọ wọn wà ninu àkọsílẹ̀ ìdílé àwọn Lefi.


Hesekaya pín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, olukuluku ní iṣẹ́ tirẹ̀. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi wà fún ẹbọ sísun, ati ẹbọ alaafia. Àwọn náà ni wọ́n wà fún ati máa ṣe iṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ OLUWA, ati láti máa kọrin ọpẹ́ ati ìyìn sí OLUWA.


Gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dafidi fi lélẹ̀, Solomoni pín àwọn alufaa sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn, ó sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti máa kọ orin ìyìn ati láti máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn alufaa ninu iṣẹ́ wọn ojoojumọ. Ó yan àwọn aṣọ́nà sí oríṣìíríṣìí ẹnu ọ̀nà gẹ́gẹ́ bí Dafidi eniyan Ọlọrun ti pa á láṣẹ.


Wọ́n sì fi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ipò wọn ninu iṣẹ́ ìsìn inú Tẹmpili, ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé Mose.


“Lẹ́yìn náà, pe Aaroni arakunrin rẹ sọ́dọ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ wọnyi: Nadabu, Abihu, Eleasari, ati Itamari. Yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n sì jẹ́ alufaa mi.


Gbé àwọn ẹ̀wù náà wọ Aaroni arakunrin rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì ta òróró sí wọn lórí láti yà wọ́n sọ́tọ̀ ati láti yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi.


“Ohun tí o óo ṣe láti ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sọ́tọ̀ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi nìyí: mú ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kan, ati àgbò meji tí kò ní àbùkù,


N óo ya àgọ́ àjọ ati pẹpẹ náà sí mímọ́, ati Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu, kí wọ́n lè máa sìn mí gẹ́gẹ́ bí alufaa.


dì wọ́n lámùrè, kí o sì dé wọn ní fìlà. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, atọmọdọmọ wọn yóo sì máa ṣe alufaa mi.


Ta òróró yìí sí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lórí, kí o fi yà wọ́n sí mímọ́; kí wọ́n lè máa ṣe alufaa fún mi.


Ṣugbọn ìwọ pẹlu àwọn ọmọ rẹ nìkan ni alufaa ti yóo máa ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ ati níbi aṣọ ìbòjú. Èyí ni yóo jẹ́ iṣẹ́ yín nítorí ẹ̀bùn ni mo fi iṣẹ́ alufaa ṣe fun yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ yóo kú.”


Ní àkókò Hẹrọdu, ọba Judia, alufaa kan wà tí ń jẹ́ Sakaraya, ní ìdílé Abiya. Orúkọ iyawo rẹ̀ ni Elisabẹti, láti inú ìdílé Aaroni.


Ṣugbọn wọn kò ní ọmọ, nítorí pé Elisabẹti yàgàn. Àwọn mejeeji ni wọ́n sì ti di arúgbó.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan