Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 1:71 - Yoruba Bible

71 pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ó kórìíra wa;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

71 Pe, a o gbà wa là lọwọ awọn ọtá wa, ati lọwọ gbogbo awọn ti o korira wa;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

71 Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 1:71
19 Iomraidhean Croise  

ṣugbọn kí wọn bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun wọn, yóo sì gbà wọ́n lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn.


Ó gbà wọ́n là lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra wọn, ó sì kó wọn yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.


Gbà wá, OLUWA, Ọlọrun wa, kí o sì kó wa kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kí á lè máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí á sì lè máa ṣògo ninu ìyìn rẹ.


Juda yóo rí ìgbàlà ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo sì wà láìléwu. Orúkọ tí a óo máa pè é ni ‘OLUWA ni òdodo wa.’


n óo kó àwọn eniyan ibẹ̀ jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti fi ibinu, ìrúnú, ati ìkanra lé wọn lọ; n óo kó wọn pada sí ibí yìí, n óo sì mú kí wọn máa gbé ní àìléwu.


Wọn óo máa gbé ibẹ̀ láìbẹ̀rù; wọn óo kọ́ ilé, wọn óo sì ṣe ọgbà àjàrà, wọn óo máa gbé láìbẹ̀rù nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n yí wọn ká, tí wọ́n sì ti kẹ́gàn wọn. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.”


N óo bá wọn dá majẹmu alaafia; n óo lé àwọn ẹranko burúkú kúrò ní ilẹ̀ náà, wọn yóo máa gbé inú aṣálẹ̀ ati inú igbó láìléwu.


Wọn kò ní jẹ́ ìjẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹranko ilẹ̀ yìí kò ní pa wọ́n jẹ mọ́. Wọn óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, ẹnìkan kan kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́.


Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́ a óo ko yín jọ. Ní ọdún mélòó kan sí i, ẹ óo gbógun ti ilẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ̀ sípò lẹ́yìn ìparun ogun, orílẹ̀-èdè tí a ṣà jọ láti ààrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè mìíràn sórí àwọn òkè ńláńlá Israẹli, ilẹ̀ tí ó ti wà ní ahoro fún ọpọlọpọ ọdún. Láti inú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ni a ti ṣa àwọn eniyan rẹ̀ jọ; nisinsinyii, gbogbo wọn wà láìléwu.


Kí á yin Oluwa Ọlọrun Israẹli nítorí ó ti mú ìrànlọ́wọ́ wá fún àwọn eniyan rẹ̀, ó sì ti dá wọn nídè.


pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ati pé yóo fún wa ní anfaani láti máa sìn ín láì fòyà,


Ẹ máa fò fún ayọ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ta ló tún dàbí yín, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí OLUWA tìkalárarẹ̀ gbàlà? OLUWA tìkalárarẹ̀ ni ààbò yín, ati idà yín, òun ní ń dáàbò bò yín, tí ó sì ń fun yín ní ìṣẹ́gun. Àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa wá bẹ̀bẹ̀ fún àánú, ẹ óo sì máa tẹ àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn mọ́lẹ̀.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń hùwà ẹ̀ṣẹ̀, láti ọ̀dọ̀ Èṣù ni ó ti wá, nítorí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé ni Èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọrun ṣe wá, kí ó lè pa àwọn iṣẹ́ Èṣù run.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan