Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 1:7 - Yoruba Bible

7 Ṣugbọn wọn kò ní ọmọ, nítorí pé Elisabẹti yàgàn. Àwọn mejeeji ni wọ́n sì ti di arúgbó.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ṣugbọn nwọn kò li ọmọ, nitoriti Elisabeti yàgan, awọn mejeji si di arugbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí tí Elisabeti yàgàn; àwọn méjèèjì sì di arúgbó.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 1:7
16 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Abrahamu dojúbolẹ̀, ó búsẹ́rìn-ín, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Ọkunrin tí ó ti di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ha tún lè bímọ bí? Sara, tí ó ti di ẹni aadọrun-un ọdún ha tún lè bímọ bí?”


Abrahamu ati Sara ti di àgbàlagbà ní àkókò yìí, ogbó ti dé sí wọn, ọjọ́ ti pẹ́ tí Sara ti rí nǹkan oṣù rẹ̀ kẹ́yìn.


Isaaki gbadura sí OLUWA fún aya rẹ̀ tí ó yàgàn, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, Rebeka aya rẹ̀ sì lóyún.


Nígbà tí Rakẹli rí i pé òun kò bímọ fún Jakọbu rárá, ó bẹ̀rẹ̀ sí jowú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ó wí fún Jakọbu pé, “Tí o kò bá fẹ́ kí n kú sí ọ lọ́rùn, fún mi lọ́mọ.”


Ní àkókò yìí, Dafidi ọba ti di arúgbó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣọ tí ó nípọn ni wọ́n fi ń bò ó, òtútù a tún máa mú un.


Eliṣa bá bèèrè lọ́wọ́ Gehasi pé, “Kí ni mo lè ṣe fún un nígbà náà?” Gehasi ní, “Kò bímọ, ọkọ rẹ̀ sì ti di arúgbó.”


Ní àkókò Hẹrọdu, ọba Judia, alufaa kan wà tí ń jẹ́ Sakaraya, ní ìdílé Abiya. Orúkọ iyawo rẹ̀ ni Elisabẹti, láti inú ìdílé Aaroni.


Àwọn mejeeji ń rìn déédé níwájú Ọlọrun, wọ́n ń pa gbogbo àwọn àṣẹ ati ìlànà Oluwa mọ́ láì kùnà.


Nígbà tí ó yá, ó kan ìpín àwọn Sakaraya láti wá ṣe iṣẹ́ alufaa níwájú Ọlọrun ninu Tẹmpili.


Igbagbọ rẹ̀ kò yẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ro ti ara rẹ̀ tí ó ti di òkú tán, (nítorí ó ti tó ẹni ọgọrun-un ọdún) ó tún ro ti Sara tí ó yàgàn.


Nípa igbagbọ, Abrahamu ní agbára láti bímọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sara yàgàn, ó sì ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí, Abrahamu gbà pé ẹni tí ó ṣèlérí tó gbẹ́kẹ̀lé.


Iyawo meji ni Elikana yìí ní. Ọ̀kan ń jẹ́ Hana, ekeji sì ń jẹ́ Penina. Penina bímọ, ṣugbọn Hana kò bí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan