Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 1:6 - Yoruba Bible

6 Àwọn mejeeji ń rìn déédé níwájú Ọlọrun, wọ́n ń pa gbogbo àwọn àṣẹ ati ìlànà Oluwa mọ́ láì kùnà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Awọn mejeji si ṣe olododo niwaju Ọlọrun, nwọn nrìn ni gbogbo ofin on ìlana Oluwa li ailẹgan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 1:6
33 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Abramu di ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un, OLUWA farahàn án, ó sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa gbọ́ tèmi, kí o sì jẹ́ pípé.


Ìtàn ìran Noa nìyí: Noa jẹ́ olódodo, òun nìkan ṣoṣo ni eniyan pípé ní àkókò tirẹ̀, ó sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu OLUWA.


Nígbà tí ó yá OLUWA sọ fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ, nítorí pé ìwọ nìkan ni o jẹ́ olódodo sí mi ní gbogbo ayé.


Ìdí rẹ̀ ni pé, Dafidi ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, kò sì ṣàìgbọràn sí àṣẹ rẹ̀ rí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, (àfi ohun tí ó ṣe sí Uraya ará Hiti).


Bí o bá sìn mí tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ, ti ṣe, bí o bá ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ, tí o sì pa òfin ati ìlànà mi mọ́,


“Mo bẹ̀ ọ́ OLUWA, ranti bí mo ti sìn ọ́ pẹlu òtítọ́ ati ọkàn pípé, ati bí mo ti ń ṣe ohun tí o fẹ́.” Ó sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.


Ṣugbọn ó ń sin Ọlọrun àwọn baba rẹ̀, ó pa òfin Ọlọrun mọ́, kò sì tẹ̀lé ìṣe àwọn ọmọ Israẹli.


Ọkunrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jobu; ó ń gbé ilẹ̀ Usi, ó jẹ́ olódodo ati olóòótọ́ eniyan, ó bẹ̀rù Ọlọrun, ó sì kórìíra ìwà burúkú.


OLUWA tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí ẹni tí ó jẹ́ olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé, ati pé ó bẹ̀rù èmi OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú?”


“Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí, ṣugbọn báwo ni ẹlẹ́ran ara ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?


Òun ni ojú kò fi ní tì mí, nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé.


Ṣugbọn wọn kò ní ọmọ, nítorí pé Elisabẹti yàgàn. Àwọn mejeeji ni wọ́n sì ti di arúgbó.


Ó wá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń dá ara yín láre lójú eniyan, ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkàn yín. Ohun tí eniyan ń gbé gẹ̀gẹ̀, ohun ẹ̀gbin ni lójú Ọlọrun.


Ọkunrin kan wà ní Jerusalẹmu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simeoni. Ó jẹ́ olódodo eniyan ati olùfọkànsìn, ó ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo tu Israẹli ninu. Ẹ̀mí Mímọ́ wà pẹlu rẹ̀.


Nítorí Dafidi sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Mo rí Oluwa níwájú mi nígbà gbogbo, ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi nítorí náà ohunkohun kò lè dà mí láàmú.


Paulu kọjú sí àwọn ìgbìmọ̀, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ní gbogbo ìgbé-ayé mi, ọkàn mí mọ́ níwájú Ọlọrun títí di òní.”


Ìdí nìyí tí mo fi ń sa ipá mi kí ọkàn mi lè jẹ́ mi lẹ́rìí pé inú mi mọ́ sí Ọlọrun ati eniyan nígbà gbogbo.


O kò ní ipa tabi ìpín ninu ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ọkàn rẹ kò tọ́ níwájú Ọlọrun.


Ọlọrun ṣe èyí kí á lè tẹ̀lé ìlànà Òfin ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àní àwa tí ìhùwàsí wa kì í ṣe bíi tí ẹni tí ẹran-ara ń lò ṣugbọn bí àwọn ẹni tí Ẹ̀mí ń darí.


Mo yìn yín nítorí pé ẹ̀ ń ranti mi nígbà gbogbo, ati pé ẹ kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀kọ́ tí mo fi kọ yín látijọ́ bọ́ lọ́wọ́ yín.


Nǹkankan wà tí a lè fi ṣe ìgbéraga, ẹ̀rí-ọkàn wa sì jẹ́rìí sí i pé pẹlu ọkàn kan ati inú kan níwájú Ọlọrun ni a fi ń bá gbogbo eniyan lò, pàápàá jùlọ ẹ̀yin gan-an. Kì í ṣe ọgbọ́n eniyan bíkòṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.


Gbogbo ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín là sílẹ̀ ni kí ẹ máa tọ̀, kí ẹ lè wà láàyè, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ óo gbà.


kí ẹ lè jẹ́ Ọmọ Ọlọrun, tí kò lẹ́bi tí kò sì ní àléébù, ọmọ Ọlọrun tí ó pé, láàrin àwọn ìran tí ọ̀nà wọn wọ́, tí ìwà wọn sì ti bàjẹ́. Láàrin irú àwọn eniyan wọnyi ni ẹ̀ ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ ninu ayé,


ni Ọlọrun wá mú wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara rẹ̀ nípa ikú ọmọ rẹ̀, kí ó lè sọ yín di ẹni tí ó mọ́, tí kò ní àbùkù, tí kò sì ní ẹ̀sùn níwájú rẹ̀,


Kí Oluwa fi agbára fun yín, kí ọkàn yín lè wà ní ipò mímọ́, láìní àléébù, níwájú Ọlọrun Baba wa nígbà tí Oluwa wa Jesu bá farahàn pẹlu gbogbo àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.


Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, nígbà tí ẹ̀ ń retí nǹkan wọnyi, ẹ máa ní ìtara láti wà láì lábùkù ati láì lábàwọ́n, kí ẹ wà ní alaafia pẹlu Ọlọrun.


Bí ẹ bá mọ̀ pé olódodo ni, ẹ mọ̀ pé gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo ni ọmọ rẹ̀.


Ọ̀nà tí a fi lè mọ̀ pé a mọ Ọlọrun ni pé bí a bá ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.


Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe òdodo ni olódodo, bí Jesu ti jẹ́ olódodo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan