Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 1:51 - Yoruba Bible

51 Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fi agbára rẹ̀ hàn, ó tú àwọn tí ó gbéraga ninu ọkàn wọn ká.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

51 O ti fi agbara hàn li apa rẹ̀; o ti tú awọn onirera ká ni ironu ọkàn wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

51 Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀; o ti tú àwọn onígbèéraga ká ní ìrònú ọkàn wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 1:51
32 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fọ́n wọn káàkiri sí gbogbo orílẹ̀ ayé, wọ́n pa ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó tì.


Nígbà tí OLUWA rí i pé ìwà burúkú eniyan ti pọ̀ jù láyé, ati pé kìkì ibi ni èrò inú wọn nígbà gbogbo,


Nígbà tí OLUWA gbọ́ òórùn dídùn ẹbọ náà, ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “N kò ní fi ilẹ̀ gégùn-ún mọ́ nítorí eniyan, nítorí pé, láti ìgbà èwe wọn wá ni èrò inú wọn ti jẹ́ kìkì ibi. Bẹ́ẹ̀ ni n kò ní pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run mọ́ bí mo ti ṣe yìí.


Ẹ gbọ́ orin ayọ̀ ìṣẹ́gun, ninu àgọ́ àwọn olódodo. “Ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá.


OLUWA sọ ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè di asán; ó sì mú kí ètò àwọn eniyan já sófo.


N óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae, nítorí ohun tí o ṣe, n óo máa kéde orúkọ rẹ níwájú àwọn olùfọkànsìn rẹ, nítorí pé ó dára bẹ́ẹ̀.


Ẹ̀mí mi yóo ní ànító ati àníṣẹ́kù; n óo sì fi ayọ̀ kọ orin ìyìn sí ọ.


Ìwọ ni o wó Rahabu mọ́lẹ̀ bí òkú ẹran; o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká.


Alágbára ni ọ́; agbára ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; o gbé ọwọ́ agbára rẹ sókè.


Ẹ kọ orin titun sí OLUWA, nítorí tí ó ti ṣe ohun ìyanu; agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati apá mímọ́ rẹ̀ ni ó fi ṣẹgun.


Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ó ti gba àwọn eniyan náà lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, nígbà tí àwọn ará Ijipti ń lò wọ́n ní ìlò àbùkù ati ẹ̀gàn.”


Ẹ wò ó! OLUWA Ọlọrun ń bọ̀ pẹlu agbára ipá rẹ̀ ni yóo fi máa ṣe àkóso. Ẹ wò ó! Èrè rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀.


Jí, jí! Dìde, OLUWA, jí pẹlu agbára; jí bí ìgbà àtijọ́, bí o ti ṣe sí ìran wa látijọ́. Ṣebí ìwọ ni o gé Rahabu wẹ́lẹwẹ̀lẹ, tí o fi idà gún diragoni?


OLUWA yóo lo agbára mímọ́ rẹ̀, lójú àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo eniyan, títí dé òpin ayé, yóo sì rí ìgbàlà Ọlọrun wa.


Ẹni tí ó gbé agbára rẹ̀ tí ó lógo wọ Mose, tí ó pín òkun níyà níwájú wọn, kí orúkọ rẹ̀ lè lókìkí títí lae.


Nítorí pé n óo sọ ọ́ di kékeré láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, o óo sì di yẹpẹrẹ, láàrin àwọn ọmọ eniyan.


“Ẹ gbọ́, èmi Nebukadinesari, fi ìyìn, ògo, ati ọlá fún ọba ọ̀run. Nítorí pé gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ pé, ọ̀nà rẹ̀ tọ́, ó sì lè rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀.”


Wọ́n mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò júbà rẹ̀ bí Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, gbogbo èrò wọn di asán, òye ọkàn wọn sì ṣókùnkùn.


ati gbogbo ìdínà tí ó bá gbórí sókè tí ó lòdì sí ìmọ̀ Ọlọrun. A mú gbogbo èrò ọkàn ní ìgbèkùn kí ó lè gbọ́ràn sí Kristi lẹ́nu.


Tabi pé, oriṣa kan ti dìde rí, tí ó gbìdánwò àtifi ipá gba orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹlu àmì rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu, ati ogun, ati agbára ati àwọn nǹkan tí ó bani lẹ́rù, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ojú yín rí i tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe fun yín ní Ijipti?


Bákan náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa tẹríba fún àwọn àgbà. Gbogbo yín, ẹ gbé ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀, bí ẹ ti ń bá ara yín lò, nítorí, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.”


Nítorí èyí, ní ọjọ́ kan náà ni oríṣìíríṣìí òfò yóo dé bá a, ati àjàkálẹ̀ àrùn, ati ọ̀fọ̀, ati ìyàn. Iná yóo tún jó o ní àjórun, nítorí alágbára ni Oluwa Ọlọrun tí ó ti ń ṣe ìdájọ́ fún un.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan