Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 1:2 - Yoruba Bible

2 àwọn tí nǹkan wọnyi ṣojú wọn, tí wọ́n sì sọ fún wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ani gẹgẹ bi awọn ti o ṣe oju wọn lati ibẹrẹ, ti nwọn si jasi iranṣẹ ọrọ na, ti fi le wa lọwọ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó ṣe ojú wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ ti fi lé wa lọ́wọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 1:2
25 Iomraidhean Croise  

Bí ìyìn rere Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí:


Nígbà tí wọ́n túká lọ, wọ́n ń waasu ní ibi gbogbo, Oluwa ń bá wọ́n ṣiṣẹ́, ó ń fi ìdí ọ̀rọ̀ ìyìn rere múlẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ń bá wọn lọ.]


Afunrugbin fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ ìròyìn ayọ̀.


Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọnyi.


Ẹ̀yin náà yóo sì jẹ́rìí mi nítorí ẹ ti wà pẹlu mi láti ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mi.


Ṣugbọn mo ti sọ gbogbo nǹkan wọnyi fun yín, kí ẹ lè ranti pé mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, nígbà tí ó bá yá, tí wọn bá ń ṣe é si yín. “N kò sọ àwọn nǹkan wọnyi fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀ nítorí mo wà lọ́dọ̀ yín.


Àwọn aposteli yìí ni ó fi ara rẹ̀ hàn láàyè lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀ pẹlu ẹ̀rí tí ó dájú. Wọ́n rí i níwọ̀n ogoji ọjọ́, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti ìjọba Ọlọrun.


Ṣugbọn ẹ̀yin yóo gba agbára nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé yin. Ẹ óo wá máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo Judia ati ní Samaria ati títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”


Nígbà tí wọ́n ti waasu ìyìn rere ní Pega, wọ́n lọ sébùúté ní Atalia.


Wọ́n gba ilẹ̀ Firigia ati Galatia kọjá. Ẹ̀mí Mímọ́ kò gbà wọ́n láàyè láti lọ waasu ọ̀rọ̀ Oluwa ní Esia.


Àwọn yìí ṣe onínú rere ju àwọn Juu ti Tẹsalonika lọ. Wọ́n fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Lojoojumọ ni wọ́n ń wá inú Ìwé Mímọ́ wò láti rí bí àwọn ohun tí wọ́n kọ́ wọn rí bẹ́ẹ̀.


Dìde nàró. Ohun tí mo fi farahàn ọ́ nìyí: mo ti yàn ọ́ láti jẹ́ iranṣẹ mi, kí o lè jẹ́rìí ohun tí o rí, ati ohun tí n óo fihàn ọ́.


Ní tiwa, a kò lè ṣe aláìsọ ohun tí a ti rí ati ohun tí a ti gbọ́.”


Àwọn tí wọ́n túká bá ń lọ káàkiri, wọ́n ń waasu ọ̀rọ̀ náà.


láti jẹ́ iranṣẹ Kristi Jesu sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu. Mò ń ṣe iṣẹ́ alufaa láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi nípa wiwaasu ìyìn rere Ọlọrun, kí wọ́n lè jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọrun, ọrẹ tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti yà sí mímọ́.


Bí ó ti yẹ kí eniyan máa rò nípa wa ni pé a jẹ́ iranṣẹ Kristi ati ìríjú àwọn nǹkan àṣírí Ọlọrun.


báwo ni a óo ti ṣe sá àsálà, tí a bá kọ etí-ikún sí ìgbàlà tí ó tóbi tó báyìí? Oluwa fúnrarẹ̀ ni ó kọ́kọ́ kéde ìgbàlà yìí ní ìbẹ̀rẹ̀. Àwọn tí wọ́n gbọ́ ni wọ́n fún wa ní ìdánilójú pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí.


Nítorí náà, mo bẹ àwọn àgbà láàrin yín, alàgbà ni èmi náà, ati ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, n óo sì ní ìpín ninu ògo tí yóo farahàn.


Kì í ṣe ìtàn àròsọ ni a gbójú lé nígbà tí a sọ fun yín nípa agbára ati wíwá Oluwa wa Jesu Kristi, ṣugbọn ẹlẹ́rìí ọlá ńlá rẹ̀ ni a jẹ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan