Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 1:11 - Yoruba Bible

11 Angẹli Oluwa kan bá yọ sí i, ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún pẹpẹ turari.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Angẹli Oluwa kan si fi ara hàn a, o duro li apa ọtún pẹpẹ turari.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Angẹli Olúwa kan sì fi ara hàn án, ó dúró ní apá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 1:11
15 Iomraidhean Croise  

Yóo da turari náà sórí iná níwájú OLUWA, kí èéfín turari náà lè bo ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí, kí Aaroni má baà kú.


Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Geburẹli ni orúkọ mi, èmi ni mo máa ń dúró níwájú Ọlọrun. Ọlọrun ló rán mi láti bá ọ sọ̀rọ̀, ati láti sọ nǹkan ayọ̀ yìí fún ọ.


Angẹli náà wọlé tọ Maria lọ, ó kí i, ó ní “Alaafia ni fún ọ! Ìwọ ẹni tí Ọlọrun kọjú sí ṣe ní oore, Oluwa wà pẹlu rẹ.”


Ṣugbọn angẹli náà wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù mọ́, nítorí mo mú ìròyìn ayọ̀ ńlá fun yín wá, ayọ̀ tí yóo jẹ́ ti gbogbo eniyan.


Angẹli Oluwa kan bá yọ sí wọn, ògo Oluwa tan ìmọ́lẹ̀ yí wọn ká. Ẹ̀rù bà wọ́n gan-an.


Nígbà tí ó di òru, angẹli Oluwa ṣí ìlẹ̀kùn ilé-ẹ̀wọ̀n, ó sìn wọ́n jáde, ó sọ fún wọn pé,


Ṣebí ẹ̀mí tí ó jẹ́ iranṣẹ ni gbogbo àwọn angẹli. A rán wọn láti ṣiṣẹ́ nítorí àwọn tí yóo jogún ìgbàlà.


Angẹli kẹfa fun kàkàkí rẹ̀. Mo bá gbọ́ ohùn kan láti ara àwọn ìwo tí ó wà lára pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú Ọlọrun.


Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, angẹli OLUWA fi ara han iyawo Manoa yìí, ó wí fún un pé, “Lóòótọ́, àgàn ni ọ́, ṣugbọn o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan.


Ọlọrun gbọ́ adura Manoa, angẹli Ọlọrun náà tún pada tọ obinrin yìí wá níbi tí ó jókòó sí ninu oko; ṣugbọn Manoa, ọkọ rẹ̀, kò sí lọ́dọ̀ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan