Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 9:9 - Yoruba Bible

9 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ọ̀nà jíjìn ni àwa iranṣẹ rẹ ti wá nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, nítorí a ti gbúròó rẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó ṣe sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Nwọn si wi fun u pe, Ni ilu òkere rére li awọn iranṣẹ rẹ ti wá, nitori orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoriti awa ti gbọ́ okikí rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ṣe ni Egipti,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Wọ́n sì dáhùn pé: “Ní ilẹ̀ òkèèrè ní àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wá, nítorí orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Ejibiti,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 9:9
21 Iomraidhean Croise  

“Bákan náà, nígbà tí àlejò kan, tí kì í ṣe ọmọ Israẹli, bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè nítorí orúkọ rẹ,


Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua, Kadimieli, Bani, Haṣabineya, Ṣerebaya, Hodaya, Ṣebanaya ati Petahaya, pè wọ́n pé, “Ẹ dìde dúró kí ẹ sì yin OLUWA Ọlọrun yín lae ati laelae. Ìyìn ni fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo, tí ó ga ju gbogbo ibukun ati ìyìn lọ.”


Ẹ jẹ́ kí wọn yin orúkọ OLUWA, nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ga jù; ògo rẹ̀ sì ga ju ayé ati ọ̀run lọ.


Ẹni ìyìn títí lae ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ lókìkí, kí òkìkí rẹ̀ gba ayé kan! Amin! Amin.


Ní ìṣojú àwọn baba ńlá wọn, ó ṣe ohun ìyanu, ní ilẹ̀ Ijipti, ní oko Soani.


Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ nìkan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA, ni Ọ̀gá Ògo lórí gbogbo ayé.


Àwọn eniyan ti gbọ́, wọ́n wárìrì, jìnnìjìnnì sì dà bo gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ Filistini.


ṣugbọn ìdí pataki tí òun fi jẹ́ kí wọ́n wà láàyè ni láti fi agbára òun hàn Farao, kí wọ́n lè máa ròyìn orúkọ òun OLUWA káàkiri gbogbo ayé.


O óo pe àwọn orílẹ̀-èdè tí o kò mọ̀ rí, àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́ rí yóo sáré wá sọ́dọ̀ rẹ, nítorí OLUWA Ọlọrun rẹ, ati nítorí Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ṣe ọ́ lógo.”


“N óo sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn. N óo rán àwọn tí ó yè lára wọn sí àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn bíi: Taṣiṣi, Puti, ati Ludi, ilẹ̀ àwọn tafàtafà, ati Tubali ati Jafani, ati àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré; àwọn tí kò tíì gbọ́ òkìkí mi, tí wọn kò sì tíì rí ògo mi rí. Wọn óo sì ròyìn ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.


Nisinsinyii, bí o bá pa àwọn eniyan yìí bí ẹni tí ó pa ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gbọ́ òkìkí rẹ yóo wí pé;


Mose rán oníṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu pé, “Arakunrin rẹ ni àwa ọmọ Israẹli jẹ́, o sì mọ gbogbo àwọn ìṣòro tí ó ti dé bá wa.


Nítorí àwọn ẹ̀mí burúkú ń lọgun bí wọ́n ti ń jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan. Bẹ́ẹ̀ ni a mú ọpọlọpọ àwọn arọ ati àwọn tí wọ́n ní àbùkù ara lára dá.


Bí wọ́n bá rán iṣẹ́ alaafia pada, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn wọn fun yín, kí ẹ kó gbogbo àwọn ará ìlú náà lẹ́rú kí wọ́n sì máa sìn yín.


Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sí àwọn ìlú tí ó jìnnà sí yín, tí kì í ṣe àwọn ìlú orílẹ̀-èdè tí ó wà níhìn-ín.


ati gbogbo ohun tí ó ṣe sí àwọn ọba Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òdìkejì odò Jọdani, Sihoni ọba àwọn ará Heṣiboni ati Ogu ọba àwọn ará Baṣani tí ń gbé Aṣitarotu.”


Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta tí wọ́n ti bá àwọn eniyan náà ṣe àdéhùn, ni wọ́n gbọ́ pé nítòsí wọn ni wọ́n wà, ati pé aládùúgbò ni wọ́n.


Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní ọjọ́ kẹta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìlú wọn. Àwọn ìlú náà ni: Gibeoni, Kefira, Beeroti ati Kiriati Jearimu.


Wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Wọ́n sọ fún àwa iranṣẹ yín pé, dájúdájú, OLUWA Ọlọrun yín ti pàṣẹ fún Mose láti fun yín ní gbogbo ilẹ̀ yìí, ati láti pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀; nítorí náà ni ẹ̀rù yín ṣe bà wá. Kí ẹ má baà pa wá run ni a fi ṣe ohun tí a ṣe.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan