Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 9:8 - Yoruba Bible

8 Wọ́n sọ fún Joṣua pé “Iranṣẹ yín ni wá.” Joṣua bá dá wọn lóhùn pé, “Ta ni yín, níbo ni ẹ sì ti wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Nwọn si wi fun Joṣua pe, Iranṣẹ rẹ li awa iṣe. Joṣua si wi fun wọn pe, Tali ẹnyin? nibo li ẹnyin si ti wá?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 “Ìránṣẹ́ rẹ ní àwa í ṣe.” Wọ́n sọ fún Joṣua. Ṣùgbọ́n Joṣua béèrè, “Ta ni yín àti pé níbo ni ẹ̀yin ti wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 9:8
9 Iomraidhean Croise  

Nítorí náà, ẹni tí ó ń ṣe ìtọ́jú ààfin ati olórí ìlú pẹlu àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu ranṣẹ sí Jehu, wọ́n ní: “Iranṣẹ rẹ ni wá, a sì ti ṣetán láti ṣe ohunkohun tí o bá pa láṣẹ. A kò ní fi ẹnikẹ́ni sórí oyè, ṣe ohunkohun tí o bá rò pé ó dára.”


Bí wọ́n bá rán iṣẹ́ alaafia pada, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn wọn fun yín, kí ẹ kó gbogbo àwọn ará ìlú náà lẹ́rú kí wọ́n sì máa sìn yín.


Àwọn ará Gibeoni bá ranṣẹ sí Joṣua ní àgọ́ tí ó wà ní Giligali. Wọ́n ní, “Ẹ má fi àwa iranṣẹ yín sílẹ̀! Ẹ tètè yára wá gbà wá kalẹ̀, ẹ wá ràn wá lọ́wọ́. Nítorí pé, gbogbo àwọn ọba Amori, tí wọn ń gbé agbègbè olókè, ti kó ara wọn jọ sí wa.”


Gbogbo àwọn àgbààgbà wa ati gbogbo àwọn ará ilẹ̀ wa bá wí fún wa pé, “Ẹ wá lọ bá àwọn eniyan wọnyi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ́wọ́ fún ìrìn àjò náà, ẹ wí fún wọn pé iranṣẹ yín ni wá, ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí á jọ dá majẹmu.


Nítorí náà, ẹ di ẹni ìfibú; ẹrú ni ẹ óo máa ṣe, ẹ̀yin ni ẹ óo máa ṣẹ́ igi tí ẹ óo sì máa pọnmi fun ilé Ọlọrun mi.”


Sibẹsibẹ, ọwọ́ yín náà ni a ṣì wà; ẹ ṣe wá bí ó bá ti tọ́ lójú yín.”


Ṣugbọn láti ọjọ́ náà ni Joṣua ti sọ wọ́n di ẹni tí ó ń ṣẹ́ igi, tí ó sì ń pọn omi fún àwọn eniyan Israẹli, ati fún pẹpẹ OLUWA. Títí di òní, àwọn ni wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà ní ibi tí OLUWA yàn pé kí àwọn ọmọ Israẹli ti máa jọ́sìn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan