Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 9:5 - Yoruba Bible

5 wọ́n wọ sálúbàtà tí ó ti gbó ati aṣọ àkísà, gbogbo oúnjẹ tí wọn mú lọ́wọ́ ni ó ti gbẹ, tí ó sì ti bu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ati bàta gbigbo ati lilẹ̀ li ẹsẹ̀ wọn, ati ẹ̀wu gbigbo li ara wọn; ati gbogbo àkara èse wọn o gbẹ o si hùkasi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Àwọn ọkùnrin náà sì wọ bàtà àti aṣọ tí ó ti gbó. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n pèsè fún ara wọn sì bu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 9:5
7 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn baba náà sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, ‘Ẹ tètè mú aṣọ tí ó dára jùlọ wá, kí ẹ fi wọ̀ ọ́. Ẹ fi òrùka sí i lọ́wọ́, ẹ fún un ní bàtà kí ó wọ̀.


Odidi ogoji ọdún ni mo fi ko yín la ààrin aṣálẹ̀ kọjá. Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni bàtà kò gbó mọ yín lẹ́sẹ̀.


Ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn rẹ̀ yóo jẹ́ irin ati idẹ, bí iye ọjọ́ orí rẹ̀ bá ti tó, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóo pọ̀ tó.”


Ẹ wò ó! Burẹdi wa nìyí, ó gbóná nígbà tí a dì í nílé fún ìrìn àjò yìí ní ọjọ́ tí a bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti gbẹ, ó sì ti bu.


Titun ni àwọn awọ ìpọnmi wọnyi nígbà tí a kó wọn jáde tí a sì pọn omi sinu wọn. Ẹ wò ó, wọ́n ti gbó, wọ́n sì ti ya. Àwọn aṣọ wa ati àwọn bàtà wa ti gbó nítorí ìrìn àjò náà jìn.”


wọ́n lo ọgbọ́n, wọ́n tọ́jú oúnjẹ, wọ́n mú àwọn àpò ìdọ̀họ tí wọ́n ti gbó, wọ́n dì wọ́n lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Wọ́n mú awọ ìpọnmi tí ó ti gbó, tí wọ́n sì ti lẹ̀,


Wọ́n tọ Joṣua lọ ninu àgọ́ tí ó wà ní Giligali, wọ́n wí fún òun ati àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ọ̀nà jíjìn ni a ti wá, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á dá majẹmu.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan