Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 9:4 - Yoruba Bible

4 wọ́n lo ọgbọ́n, wọ́n tọ́jú oúnjẹ, wọ́n mú àwọn àpò ìdọ̀họ tí wọ́n ti gbó, wọ́n dì wọ́n lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Wọ́n mú awọ ìpọnmi tí ó ti gbó, tí wọ́n sì ti lẹ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Nwọn ṣe ẹ̀tan, nwọn si lọ nwọn si ṣe bi ẹnipe onṣẹ ni nwọn, nwọn si mú ogbologbo àpo kà ori kẹtẹkẹtẹ wọn, ati ìgo-awọ ọti-waini ti lailai, ti o ya, ti a si dì;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 wọ́n dá ọgbọ́n ẹ̀tàn. Wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí aṣojú tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn kún fún ẹrù tí a fi àwọn àpò tó ti gbó dì, àti àwọn awọ ọtí wáìnì tó ti gbó tí a tún rán.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 9:4
12 Iomraidhean Croise  

Ọgbọ́n ẹ̀tàn ni àwọn ọmọ Jakọbu fi dá Ṣekemu ati Hamori, baba rẹ̀ lóhùn, nítorí bíbà tí ó ba Dina, arabinrin wọn jẹ́.


Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì, sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ.


“Ẹ ṣe akiyesi pé mò ń ran yín lọ bí aguntan sáàrin ìkookò. Nítorí náà ẹ gbọ́n bí ejò, kí ẹ sì níwà tútù bí àdàbà.


Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ògbólógbòó àpò awọ náà yóo bẹ́; ati ọtí ati àpò yóo sì ṣòfò. Ṣugbọn ninu àpò awọ titun ni à ń fi ọtí titun sí, ati ọtí ati àpò yóo wà ní ìpamọ́.”


Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí náà yóo bẹ́ àpò náà, ati ọtí ati àpò yóo bá ṣòfò. Ṣugbọn inú àpò awọ titun ni à ń fi ọtí titun sí.”


“Ọ̀gá ọmọ-ọ̀dọ̀ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ náà yìn ín nítorí pé ó gbọ́n. Nítorí àwọn ọmọ ayé yìí mọ ọ̀nà ọgbọ́n tí wọ́n fi ń bá ara wọn lò ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ.


Ẹ wò ó! Burẹdi wa nìyí, ó gbóná nígbà tí a dì í nílé fún ìrìn àjò yìí ní ọjọ́ tí a bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti gbẹ, ó sì ti bu.


Titun ni àwọn awọ ìpọnmi wọnyi nígbà tí a kó wọn jáde tí a sì pọn omi sinu wọn. Ẹ wò ó, wọ́n ti gbó, wọ́n sì ti ya. Àwọn aṣọ wa ati àwọn bàtà wa ti gbó nítorí ìrìn àjò náà jìn.”


Ṣugbọn nígbà tí àwọn ará Gibeoni gbọ́ ohun tí Joṣua ṣe sí ìlú Jẹriko ati Ai,


wọ́n wọ sálúbàtà tí ó ti gbó ati aṣọ àkísà, gbogbo oúnjẹ tí wọn mú lọ́wọ́ ni ó ti gbẹ, tí ó sì ti bu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan