Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 9:1 - Yoruba Bible

1 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà ní agbègbè olókè, ní òdìkejì odò Jọdani ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní etí òkun Mẹditarenia ní agbègbè Lẹbanoni, àwọn ará Hiti, àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi, gbọ́ nípa ìṣẹ́gun àwọn ọmọ Israẹli,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba ti mbẹ li apa ihin Jordani, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni gbogbo àgbegbe okun nla ti o kọjusi Lebanoni, awọn Hitti, ati awọn Amori, awọn Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi, gbọ́ ọ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nísinsin yìí, nígbà tí gbogbo ọba tó wà ní ìwọ̀-oòrùn Jordani gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, àwọn náà tí ó wà ní orí òkè àti àwọn tí ó wà ní ẹsẹ̀ òkè, àti gbogbo àwọn tí ó wà ní agbègbè Òkun ńlá títí ó fi dé Lebanoni (àwọn ọba Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti Jebusi)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 9:1
32 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí apá gúsù. Wọ́n dé ìlú olódi ti Tire, títí lọ dé gbogbo ìlú àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Kenaani. Níkẹyìn, wọ́n wá sí Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù Juda.


Nígbà tí angẹli mi bá ń lọ níwájú rẹ, tí ó bá mú ọ dé ilẹ̀ àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Perisi, ati ti àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí mo bá sì pa wọ́n run,


Ilẹ̀ yín yóo lọ títí kan Òkun Pupa, ati títí lọ kan òkun àwọn ará Filistia, láti aṣálẹ̀ títí lọ kan odò Yufurate, nítorí pé n óo fi àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà le yín lọ́wọ́, ẹ óo sì lé wọn jáde.


Mo ṣèlérí pé n óo yọ wọ́n kúrò ninu ìpọ́njú Ijipti. N óo kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Perisi ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.


“Máa pa àwọn òfin tí mo fún ọ lónìí yìí mọ́. N óo lé àwọn ará Hamori ati àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, jáde kúrò níwájú rẹ.


Àwọn ará Amaleki ń gbé ìhà gúsù ilẹ̀ náà. Àwọn ará Hiti, ará Jebusi ati àwọn ará Amori ń gbé àwọn agbègbè olókè. Àwọn ará Kenaani sì ń gbé lẹ́bàá òkun ati ní agbègbè Jọdani.”


“Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Òkun ni yóo jẹ́ ààlà yín.


Ó ní kí á dìde, kí á bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí agbègbè olókè ti àwọn ará Amori, ati gbogbo agbègbè tí ó yí wọn ká ní Araba, ní àwọn agbègbè olókè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, ati èyí tí ó wà létí òkun tí wọn ń pè ní Mẹditarenia, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Lẹbanoni, títí dé odò ńlá nnì, àní odò Yufurate.


Mo bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí n kọjá sí òdìkejì Jọdani kí n sì rí ilẹ̀ dáradára náà, agbègbè olókè dáradára nnì ati Lẹbanoni.’


ati gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani títí dé Òkun Araba, tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀, tí ó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Pisiga.


“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá ko yín wọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ yìí, tí ẹ bá gba ilẹ̀ náà, tí OLUWA sì lé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè jáde fun yín, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Hiti, Girigaṣi, Amori, Kenaani, Perisi, Hifi, Jebusi, àní àwọn orílẹ̀-èdè meje tí wọ́n tóbi jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ;


títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti fun yín, tí wọn yóo sì fi gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fún wọn. Nígbà náà ni ẹ óo tó pada sí orí ilẹ̀ yín, tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fun yín ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani, ẹ óo sì máa gbé ibẹ̀.”


Láti inú aṣálẹ̀ ati òkè Lẹbanoni yìí lọ, títí dé odò ńlá náà, odò Yufurate, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Hiti, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn, ni yóo jẹ́ ilẹ̀ yín.


Wọ́n bá kó wọn jáde, láti inú ihò: ọba Jerusalẹmu, ọba Heburoni, ọba Jarimutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egiloni.


Láti òkè Halaki títí lọ sí Seiri, títí dé Baaligadi ní àfonífojì Lẹbanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni. Ó mú gbogbo àwọn ọba wọn, ó pa wọ́n.


ati ilẹ̀ àwọn ará Gebali, gbogbo Lẹbanoni ní apá ìlà oòrùn, láti Baaligadi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkè Herimoni títí dé ibodè Hamati.


Òkun yìí ni ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn. Òun ni ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.


Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun yín ti fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn; nítorí náà, ẹ pada lọ sí ilẹ̀ yín, níbi tí ohun ìní yín wà, àní ilẹ̀ tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín ní òdìkejì odò Jọdani.


Mose ti kọ́kọ́ fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ ní Baṣani; Joṣua sì fún ìdajì yòókù ní ilẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ti àwọn arakunrin wọn, ní ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani. Nígbà tí Joṣua rán wọn pada lọ sí ilé wọn, tí ó sì súre fún wọn, ó wí fún wọn pé,


Ẹ wò ó! Gbogbo ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí a kò tíì ṣẹgun, ati gbogbo àwọn tí a ti ṣẹgun ni mo ti pín fun yín gẹ́gẹ́ bí ogún yín, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọdani, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn,


Ẹ gun òkè odò Jọdani wá sí Jẹriko, àwọn ará Jẹriko sì gbógun tì yín, ati àwọn ará Amori, àwọn ará Perisi, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi, mo sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.


Èyí ni ẹ óo fi mọ̀ pé Ọlọrun alààyè wà láàrin yín, kò sì ní kùnà láti lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi, àwọn ará Perisi, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Amori, ati àwọn ará Jebusi, jáde fun yín.


Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kọjá lọ lórí ilẹ̀ gbígbẹ, àwọn alufaa tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu OLUWA dúró lórí ilẹ̀ gbígbẹ láàrin odò Jọdani, títí tí gbogbo àwọn eniyan náà fi la odò Jọdani kọjá.


Nígbà tí gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Amori, tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, ati gbogbo ọba àwọn ará ilẹ̀ Kenaani, tí wọ́n wà ní etí Òkun gbọ́ pé OLUWA mú kí odò Jọdani gbẹ nítorí àwọn ọmọ Israẹli, títí tí wọ́n fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, àyà wọn já, ìdààmú sì bá wọn, nítorí àwọn ọmọ Israẹli.


OLUWA wà pẹlu Joṣua, òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo ilẹ̀ náà.


Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli wí fún àwọn ará Hifi náà pé, “Bóyá nítòsí ibí ni ẹ ti wá, báwo ni a ṣe lè ba yín dá majẹmu?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan