Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 8:4 - Yoruba Bible

4 Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ fara pamọ́ lẹ́yìn ìlú náà, ẹ má jìnnà sí i pupọ, ṣugbọn ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 O si paṣẹ fun wọn pe, Wò o, ẹnyin o ba tì ilu na, ani lẹhin ilu na: ẹ má ṣe jìna pupọ̀ si ilu na, ṣugbọn ki gbogbo nyin ki o murasilẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Pẹ̀lú àwọn àṣẹ wọ̀nyí: “Ẹ fi etí sílẹ̀ dáradára. Ẹ ba sí ẹ̀yìn ìlú náà. Ẹ má ṣe jìnnà sí i púpọ̀. Kí gbogbo yín wà ní ìmúrasílẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 8:4
14 Iomraidhean Croise  

Ọba dìde ní òru ọjọ́ náà, ó sọ fún àwọn olórí ogun rẹ̀ pé, “Mo mọ ète àwọn ará Siria. Wọ́n mọ̀ pé ìyàn mú ninu ìlú wa, nítorí náà ni wọ́n ṣe fi ibùdó ogun wọn sílẹ̀ láti sá pamọ́ sinu igbó, pẹlu èrò pé a óo wá oúnjẹ wá. Kí wọ́n lè mú wa láàyè, kí wọ́n sì gba ìlú wa.”


Ṣugbọn Jeroboamu ti rán ọ̀wọ́ ọmọ ogun kan lọ láti kọlu àwọn ọmọ ogun Juda látẹ̀yìn. Àwọn ọmọ ogun Jeroboamu wà níwájú àwọn ọmọ ogun Juda, àwọn tí ó rán tí wọ́n sápamọ́ sì wà lẹ́yìn wọn.


Ọgbọ́n yóo mú ọlọ́gbọ́n lágbára ju ọba mẹ́wàá lọ láàrin ìlú.


Sibẹsibẹ, mo rí i pé ọgbọ́n ju agbára lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ka ọgbọ́n ọkunrin yìí kún, tí kò sì sí ẹni tí ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.


Ẹ má gbà fún wọn. Nítorí àwọn kan ninu wọn yóo dènà dè é, wọ́n ju ogoji lọ. Wọ́n ti búra pé àwọn kò ní jẹun, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kò ní mu omi títí àwọn yóo fi pa Paulu. Bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ti múra tán. Ohun tí wọn ń retí ni kí ẹ ṣe ìlérí pé ẹ óo fi Paulu ranṣẹ sí ìgbìmọ̀.”


Àwọn ará Ai bá pe gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ìlú jọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ọmọ Israẹli lọ. Bí wọ́n ti ń lé Joṣua lọ ni wọ́n ń jìnnà sí ìlú.


Joṣua bá múra, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí ìlú Ai. Joṣua yan ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) akikanju ọmọ ogun, ó rán wọn jáde ní alẹ́.


Àwọn ọmọ Israẹli bá fi àwọn eniyan pamọ́ ní ibùba, yípo gbogbo Gibea.


Olukuluku àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò ní ààyè rẹ̀, wọ́n lọ tò ní Baalitamari. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ba ní ibùba bá jáde kúrò níbi tí wọ́n ba sí ní apá ìwọ̀ oòrùn Geba.


Àwọn ọmọ Bẹnjamini rí i pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn. Nígbà tí, àwọn ọmọ Israẹli ṣebí ẹni ń sá lọ fún àwọn ara Bẹnjamini, wọ́n ń tàn wọ́n jáde ni, wọ́n sì ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ará wọn tí wọ́n ba ní ibùba yípo Gibea láti gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini.


Àwọn ará ìlú Ṣekemu bá rán àwọn kan ninu wọn, wọ́n lọ ba ní ibùba ní orí òkè de Abimeleki. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dá gbogbo àwọn tí wọn ń kọjá lọ́nà; ni ìròyìn bá kan Abimeleki.


Nítorí náà, tí ó bá di òru, kí ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lọ ba níbùba.


OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo jẹ àwọn ará Amaleki níyà nítorí pé wọ́n gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti.


Òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá lọ sí ìlú Amaleki, wọ́n ba ní ibùba, ní àfonífojì.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan