Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 8:3 - Yoruba Bible

3 Joṣua bá múra, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí ìlú Ai. Joṣua yan ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) akikanju ọmọ ogun, ó rán wọn jáde ní alẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Joṣua si dide, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun, lati gòke lọ si Ai: Joṣua si yàn ẹgba mẹdogun, alagbara akọni, o si rán wọn lo li oru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun jáde lọ láti dojúkọ Ai. Ó sì yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àwọn ọkùnrin ogun rẹ̀ ti ó yakin, ó sì rán wọn lọ ní òru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 8:3
10 Iomraidhean Croise  

Mose bá wí fún Joṣua pé, “Yan àwọn akọni ọkunrin láàrin yín kí o sì jáde lọ láti bá àwọn ará Amaleki jagun lọ́la, n óo dúró ní orí òkè pẹlu ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ mi.”


Wọn kò fura títí ìkún-omi fi dé, tí ó gba gbogbo wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ ni àkókò dídé Ọmọ-Eniyan yóo rí.


ọ̀gá ẹrú náà yóo dé ní ọjọ́ tí kò rò, ati ní wakati tí kò lérò.


“Nígbà tí ó di ààrin ọ̀gànjọ́, igbe ta pé, ‘Ọkọ iyawo dé! Ẹ jáde lọ pàdé rẹ̀.’


Nítorí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ̀ dájú pé bí ìgbà tí olè bá dé lóru ni ọjọ́ tí Oluwa yóo dé yóo rí.


Joṣua bá lọ láti Giligali, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju ati akọni.


Bí o ti ṣe sí Jẹriko ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe sí Ai ati ọba rẹ̀. Ṣugbọn ẹ dá ìkógun ati àwọn ẹran ọ̀sìn tí ó wà níbẹ̀ sí, kí ẹ sì kó o gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín; ẹ ba ní ibùba lẹ́yìn odi ìlú náà.”


Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ fara pamọ́ lẹ́yìn ìlú náà, ẹ má jìnnà sí i pupọ, ṣugbọn ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀.


Ṣugbọn bí olè ni ọjọ́ Oluwa yóo dé. Ní ọjọ́ náà, àwọn ọ̀run yóo parẹ́ pẹlu ariwo ńlá bí ìgbà tí iná ńlá bá ń jó ìgbẹ́. Àwọn ẹ̀dá ojú ọ̀run yóo fò, wọ́n óo sì jóná. Ayé ati gbogbo nǹkan inú rẹ̀ yóo wá wà ní ìhòòhò.


Nítorí náà, tí ó bá di òru, kí ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lọ ba níbùba.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan