Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 8:2 - Yoruba Bible

2 Bí o ti ṣe sí Jẹriko ati ọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe sí Ai ati ọba rẹ̀. Ṣugbọn ẹ dá ìkógun ati àwọn ẹran ọ̀sìn tí ó wà níbẹ̀ sí, kí ẹ sì kó o gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín; ẹ ba ní ibùba lẹ́yìn odi ìlú náà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Iwọ o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀: kìki ikogun rẹ̀, ati ohun-ọ̀sin rẹ̀, li ẹnyin o mú ni ikogun fun ara nyin: rán enia lọ iba lẹhin ilu na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ìwọ yóò sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, ohun ìkógun wọn àti ohun ọ̀sìn wọn ni kí ẹ̀yin mú fún ara yín. Rán ènìyàn kí wọ́n ba sí ẹ̀yìn ìlú náà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 8:2
27 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn Jeroboamu ti rán ọ̀wọ́ ọmọ ogun kan lọ láti kọlu àwọn ọmọ ogun Juda látẹ̀yìn. Àwọn ọmọ ogun Jeroboamu wà níwájú àwọn ọmọ ogun Juda, àwọn tí ó rán tí wọ́n sápamọ́ sì wà lẹ́yìn wọn.


Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọrin ìyìn, OLUWA gbẹ̀yìn yọ sí àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu ati ti Òkè Seiri tí wọ́n wá bá àwọn eniyan Juda jà, ó sì tú wọn ká.


Dájúdájú, eniyan ń káàkiri bí òjìji, asán sì ni gbogbo làálàá rẹ̀; eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ ṣá, láìmọ ẹni tí yóo kó o lọ.


Eniyan rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń kó ọrọ̀ jọ fún àwọn olóòótọ́.


Olóòótọ́ yóo ní ibukun lọpọlọpọ, ṣugbọn ẹni tí ń kánjú àtilówó, kò ní lọ láìjìyà.


Bí àparò tíí pa ẹyin ẹlẹ́yin bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó fi èrú kó ọrọ̀ jọ. Ọrọ̀ yóo lọ mọ́ ọn lọ́wọ́ lọ́sàn-án gangan, nígbẹ̀yìn yóo di òmùgọ̀.


Ẹ gbé àsíá kan sókè, ẹ gbé e ti odi Babiloni; ẹ ṣe ìsénà tí ó lágbára. Ẹ fi àwọn aṣọ́nà sí ipò wọn; ẹ dira fún àwọn kan, kí wọn sápamọ́, nítorí OLUWA ti pinnu, ó sì ti ṣe ohun tí ó sọ nípa àwọn ará Babiloni.


àfi àwọn ohun ọ̀sìn tí a kó bí ìkógun, pẹlu àwọn ìkógun tí a kó ninu àwọn ìlú tí a gbà.


Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn obinrin ati àwọn ọmọ wọn sí, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo dúkìá yòókù tí ó wà ninu ìlú náà, kí ẹ kó gbogbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara yín, kí ẹ máa lo gbogbo dúkìá àwọn ọ̀tá yín tí OLUWA Ọlọrun yín ti fun yín.


Ṣugbọn OLUWA wí fún mi pé, ‘Má bẹ̀rù rẹ̀, nítorí pé mo ti fi òun ati àwọn eniyan rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́, ohun tí o ṣe sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé Heṣiboni ni kí o ṣe sí òun náà.’


Nígbà tí Adonisedeki, ọba Jerusalẹmu, gbọ́ bí Joṣua ṣe gba ìlú Ai, ati pé ó pa ìlú Ai ati ọba rẹ̀ run, bí ó ti ṣe sí ìlú Jẹriko ati ọba rẹ̀; ati pé àwọn ará Gibeoni ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia, wọ́n sì ń gbé ààrin wọn,


Ní ọjọ́ náà gan-an ni Joṣua gba ìlú Makeda, ó sì fi idà pa àwọn eniyan inú rẹ̀ ati ọba wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ ni ó parun, kò dá ẹnikẹ́ni sí. Bí ó ti ṣe sí ọba Jẹriko náà ló ṣe sí ọba Makeda.


Àwọn ọmọ Israẹli kó gbogbo dúkìá ìlú náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní ìkógun, ṣugbọn wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn eniyan ibẹ̀ run patapata, wọn kò dá ẹyọ ẹnìkan sí.


Wọ́n run gbogbo àwọn ará ìlú náà patapata: atọkunrin, atobinrin, àtọmọdé, àtàgbà, àtakọ mààlúù, ataguntan, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; gbogbo wọn ni wọ́n fi idà parun.


Joṣua ṣa nǹkan bí ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) ọmọ ogun, ó fi wọ́n pamọ́ sí ààrin Bẹtẹli ati Ai ní apá ìwọ̀ oòrùn Ai.


Nígbà tí ọba Ai ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ rí i, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ìlú náà bá yára, wọ́n jáde lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá ọ̀nà Araba láti kó ogun pàdé àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé àwọn kan ti farapamọ́ sẹ́yìn ìlú.


Gbogbo àwọn tí wọn farapamọ́ bá yára dìde ní ibi tí wọ́n wà. Bí Joṣua ti na ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sáré wọ inú ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára sọ iná sí i.


Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti fi idà pa gbogbo àwọn ará Ai tán ninu aṣálẹ̀, ní ibi tí wọ́n ti ń lé wọn lọ, wọ́n pada sí ìlú Ai, wọ́n sì fi idà pa gbogbo wọn patapata.


Joṣua bá múra, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ sí ìlú Ai. Joṣua yan ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) akikanju ọmọ ogun, ó rán wọn jáde ní alẹ́.


Ẹ̀yin ẹ dìde níbi tí ẹ farapamọ́ sí, kí ẹ sì gba ìlú náà, nítorí OLUWA Ọlọrun yóo fi lé yín lọ́wọ́.


Gbàrà tí ẹ bá ti gba ìlú náà tán, ẹ ti iná bọ̀ ọ́, kí ẹ sì ṣe bí àṣẹ OLUWA. Ó jẹ́ àṣẹ tí mo pa fun yín.”


Joṣua bá rán wọn ṣiwaju, wọ́n sì lọ sí ibi tí wọn yóo fara pamọ́ sí ní ìwọ̀ oòrùn Ai, láàrin Ai ati Bẹtẹli. Ṣugbọn Joṣua wà pẹlu àwọn eniyan ní gbogbo òru ọjọ́ náà.


Ṣugbọn nígbà tí àwọn ará Gibeoni gbọ́ ohun tí Joṣua ṣe sí ìlú Jẹriko ati Ai,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan