Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 8:10 - Yoruba Bible

10 Joṣua dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó pe gbogbo àwọn eniyan náà jọ. Òun ati àwọn àgbààgbà Israẹli ṣáájú wọn, wọ́n lọ sí Ai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Joṣua si dide ni kùtukutu owurọ̀, o si kà awọn enia, o si gòke lọ si Ai, on, ati awọn àgba Israeli niwaju awọn enia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì Joṣua kó àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, òun àti àwọn olórí Israẹli, wọ́n wọ́de ogun lọ sí Ai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 8:10
7 Iomraidhean Croise  

Abrahamu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó mú meji ninu àwọn ọdọmọkunrin ilé rẹ̀, ati Isaaki ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Ó gé igi fún ẹbọ sísun, lẹ́yìn náà wọ́n gbéra, wọ́n lọ sí ibi tí Ọlọrun ti júwe fún Abrahamu.


mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́.


Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbéra ní Akasia lọ sí etí odò Jọdani, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀ kí wọn tó la odò náà kọjá.


Joṣua dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, àwọn alufaa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA.


Joṣua gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, ó kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli wá ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, wọ́n bá mú ẹ̀yà Juda.


Gbogbo àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá a lọ títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ dé ìlú Ai, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí apá ìhà àríwá ìlú náà, odò kan ni ó wà láàrin wọn ati ìlú Ai.


Joṣua bá rán wọn ṣiwaju, wọ́n sì lọ sí ibi tí wọn yóo fara pamọ́ sí ní ìwọ̀ oòrùn Ai, láàrin Ai ati Bẹtẹli. Ṣugbọn Joṣua wà pẹlu àwọn eniyan ní gbogbo òru ọjọ́ náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan