Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 7:9 - Yoruba Bible

9 Àwọn ará Kenaani, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóo gbọ́, wọn yóo yí wa po, wọn yóo sì pa wá run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, OLUWA! Kí lo wá fẹ́ ṣe, nítorí orúkọ ńlá rẹ?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Nitoriti awọn ara Kenaani ati gbogbo awọn ara ilẹ na yio gbọ́, nwọn o si yi wa ká, nwọn o si ke orukọ wa kuro li aiye: kini iwọ o ha ṣe fun orukọ nla rẹ?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Àwọn Kenaani àti àwọn ènìyàn ìlú tí ó kù náà yóò gbọ́ èyí, wọn yóò sì yí wa ká, wọn yóò sì ké orúkọ wa kúrò ní ayé. Kí ni ìwọ ó ha ṣe fún orúkọ ńlá à rẹ?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 7:9
19 Iomraidhean Croise  

Ògo kì í ṣe fún wa, OLUWA, Kì í ṣe fún wa, orúkọ rẹ nìkan ṣoṣo ni kí á yìn lógo, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati nítorí òtítọ́ rẹ.


Ọlọrun, ìyìn rẹ tàn ká, bí orúkọ rẹ ṣe tàn dé òpin ayé, iṣẹ́ rere kún ọwọ́ rẹ.


Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọrun Olùgbàlà wa, nítorí iyì orúkọ rẹ; gbà wá, sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí orúkọ rẹ.


Wọ́n ní, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa orílẹ̀-èdè wọn run; kí á má ranti orúkọ Israẹli mọ́!”


Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ pète pèrò; wọ́n dá majẹmu láti dojú kọ ọ́.


Kí ló dé tí o óo fi jẹ́ kí àwọn ará Ijipti wí pé, o mọ̀ọ́nmọ̀ fẹ́ ṣe wọ́n níbi ni o fi kó wọn jáde láti pa wọ́n lórí òkè yìí, ati láti pa wọ́n rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé? Jọ̀wọ́, má bínú mọ, yí ọkàn rẹ pada, má sì ṣe ibi tí o ti pinnu láti ṣe sí àwọn eniyan rẹ.


Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ láàrin àwọn eniyan tí wọn ń gbé, lójú àwọn tí mo ti fi ara mi hàn wọ́n ní ilẹ̀ Ijipti, nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò níbẹ̀.


Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ. Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí, má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé, ‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ”


Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóo rí i, ojú yóo sì ti ẹni tí ń pẹ̀gàn mi pé, níbo ni OLUWA Ọlọrun mi wà? N óo fi ojú mi rí i; òun náà yóo wá di àtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ní ìta gbangba.


Mose bá sọ fún OLUWA pé, “Ní ààrin àwọn ará Ijipti ni o ti mú àwọn eniyan wọnyi jáde pẹlu agbára. Nígbà tí wọn bá sì gbọ́ ohun tí o ṣe sí wọn, wọn yóo sọ fún àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ yìí.


Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ohùn kan bá wá láti ọ̀run, ó ní, “Mo ti ṣe é lógo ná, èmi óo sì tún ṣe é lógo sí i.”


kí àwọn ará ilẹ̀ tí o ti kó wa wá má baà wí pé, ‘OLUWA kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn ati pé ó kórìíra wọn, ni ó ṣe kó wọn wá sinu aṣálẹ̀ láti pa wọ́n.


Nígbà náà ni OLUWA wí fun Joṣua pé, “Dìde. Kí ló dé tí o fi dojúbolẹ̀?


OLUWA, kí ni mo tún lè sọ, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn?


OLUWA kò ní ta eniyan rẹ̀ nù, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀, nítorí pé ó wù ú láti ṣe yín ní eniyan rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan