Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 7:7 - Yoruba Bible

7 Joṣua bá gbadura, ó ní, “Yéè! OLUWA Ọlọrun! Kí ló dé tí o fi kó àwọn eniyan wọnyi gòkè odò Jọdani láti fà wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́ láti pa wọ́n run? Ìbá tẹ́ wa lọ́rùn kí á wà ní òdìkejì odò Jọdani, kí á sì máa gbé ibẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Joṣua si wipe, Yẽ, Oluwa ỌLỌRUN, nitori kini iwọ fi mú awọn enia yi kọja Jordani, lati fi wa lé ọwọ́ awọn Amori, lati pa wa run? awa iba mọ̀ ki a joko ni ìha keji ọhún Jordani!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Joṣua sì wí pé, “Háà, Olúwa Olódùmarè, nítorí kín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá Jordani, láti fi wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, láti pa wọn run? Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdìkejì Jordani?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 7:7
19 Iomraidhean Croise  

Joramu ọba ní, “Ó mà ṣe o, OLUWA pe àwa ọba mẹtẹẹta jọ láti fi wá lé ọba Moabu lọ́wọ́.”


Mo wí ninu ìdààmú ọkàn pé, “Èké ni gbogbo eniyan.”


wọ́n ń wí pé, “Ìbá sàn kí OLUWA pa wá sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí olukuluku wa ti jókòó ti ìsaasùn ọbẹ̀ ẹran, tí a sì ń jẹ oúnjẹ àjẹyó, ju bí ẹ ti kó wa wá sí ààrin aṣálẹ̀ yìí lọ, láti fi ebi pa gbogbo wa kú.”


Ṣugbọn òùngbẹ ń gbẹ àwọn eniyan náà, wọ́n fẹ́ mu omi, wọ́n bá ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi òùngbẹ pa àwa ati àwọn ọmọ wa, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa?”


o pa àwọn eniyan rẹ ninu aṣálẹ̀ nítorí pé o kò lè kó wọn dé ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí fún wọn.


Kí ló dé tí OLUWA fi ń mú wa lọ sí ilẹ̀ náà kí àwọn ọ̀tá wa lè pa wá, kí wọ́n sì kó àwọn aya ati àwọn ọmọ wa lẹ́rú. Ǹjẹ́ kò ní sàn fún wa kí á pada sí Ijipti?”


Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran alaigbagbọ ati ìran tí ó bàjẹ́ yìí, ìgbà wo ni n óo wà lọ́dọ̀ yín dà? Ìgbà wo ni n óo sì fara dà á fun yín dà? Ẹ mú ọmọ náà wá síhìn-ín.”


Ó dá wọn lóhùn pé, “Nítorí igbagbọ yín tí ó kéré ni. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹ bá ní igbagbọ tí kò ju wóró musitadi tí ó kéré pupọ lọ, tí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbẹ̀,’ yóo sì kúrò. Kó ní sí ohun kan tí ẹ kò ní lè ṣe. [


Ẹ ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Ìwé Mímọ́ níbi tí ó ti pè yín ní ọmọ, nígbà tí ó sọ pé, Ọmọ mi, má ṣe ka ìtọ́sọ́nà Oluwa sí nǹkan yẹpẹrẹ má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá ń bá ọ wí.


Joṣua fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ hàn, òun ati àwọn àgbààgbà Israẹli dojúbolẹ̀ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì ku eruku sórí.


OLUWA, kí ni mo tún lè sọ, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn?


Wọ́n bá lọ sọkún níwájú OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n ní, “Ṣé kí á tún gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tí í ṣe àwọn arakunrin wa?” OLUWA dá wọn lóhùn pé kí wọ́n lọ gbógun tì wọ́n.


Nígbà tí wọ́n pada dé ibùdó, àwọn àgbààgbà Israẹli bèèrè pé, “Kí ló dé tí OLUWA fi jẹ́ kí àwọn ará Filistia ṣẹgun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí á lọ gbé àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní Ṣilo wá sọ́dọ̀ wa, kí ó lè máa bá wa lọ, kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan