Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 7:2 - Yoruba Bible

2 Joṣua rán àwọn ọkunrin kan láti Jẹriko lọ sí ìlú Ai, lẹ́bàá Betafeni ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe amí ilẹ̀ náà wá.” Àwọn ọkunrin náà lọ ṣe amí ìlú Ai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Joṣua si rán enia lati Jeriko lọ si Ai, ti mbẹ lẹba Beti-afeni, ni ìla-õrùn Beti-eli, o si wi fun wọn pe, Ẹ gòke lọ ki ẹ si ṣamí ilẹ na. Awọn enia na gòke lọ nwọn si ṣamí Ai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Joṣua rán àwọn ọkùnrin láti Jeriko lọ sí Ai, tí ó súnmọ́ Beti-Afeni ní ìlà-oòrùn Beteli, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè lọ kí ẹ sì ṣe ayọ́lẹ̀wò.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn arákùnrin náà lọ, wọ́n sì yọ́ Ai wò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 7:2
18 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn náà Abramu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí orí òkè tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó pàgọ́ sibẹ. Bẹtẹli wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ibùdó rẹ̀, Ai sì wà ní ìhà ìlà oòrùn. Ó tún tẹ́ pẹpẹ mìíràn níbẹ̀, ó sì sin OLUWA.


Ó sọ ibẹ̀ ní Bẹtẹli, ṣugbọn Lusi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí.


Ó gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní ìlú Bẹtẹli ó sì gbé ekeji sí ìlú Dani.


Àwọn eniyan Bẹnjamini náà ń gbé Geba lọ sókè, títí dé Mikimaṣi, Aija, Bẹtẹli, ati àwọn ìletò àyíká rẹ̀,


Ìmọ̀ràn níí fìdí ètò múlẹ̀, gba ìtọ́sọ́nà kí o tó lọ jagun.


Nítorí nípa ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n, o lè jagun, ọpọlọpọ ìmọ̀ràn níí sìí mú ìṣẹ́gun wà.


Ó ti kúrò ní agbègbè Rimoni, ó ti dé sí Aiati; ó kọjá ní Migironi, ó kó ẹrù ogun rẹ̀ jọ sí Mikimaṣi.


Sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ìwọ Heṣiboni, nítorí pé ìlú Ai ti parun! Ẹ sọkún, ẹ̀yin ọmọbinrin Raba! Ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ máa sọkún, kí ẹ sì máa sá sókè sódò láàrin ọgbà! Nítorí pé oriṣa Moleki yóo lọ sí ìgbèkùn, pẹlu àwọn babalóòṣà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ní ibi ìsìn rẹ̀.


“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ìwọ Israẹli, má kó ẹ̀bi bá Juda. Má wọ Giligali lọ bọ̀rìṣà, má sì gòkè lọ sí Betafeni, má sì lọ búra níbẹ̀ pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ.’


“Ẹ ṣe akiyesi pé mò ń ran yín lọ bí aguntan sáàrin ìkookò. Nítorí náà ẹ gbọ́n bí ejò, kí ẹ sì níwà tútù bí àdàbà.


Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra bí ẹ ti ń hùwà. Ẹ má ṣe hùwà bí ẹni tí kò gbọ́n, ṣugbọn ẹ hùwà bí ọlọ́gbọ́n.


Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun gbogbo ọba àwọn ìlú wọnyi: Jẹriko ati Ai, lẹ́bàá Bẹtẹli;


Ní apá ìhà àríwá, ààlà ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ ní etí odò Jọdani, lọ sí ara òkè ní ìhà àríwá Jẹriko. Ó gba ààrin àwọn ìlú tí wọ́n wà ní orí òkè lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì pin sí aṣálẹ̀ Betafeni.


Lẹ́yìn náà, Joṣua ọmọ Nuni rán amí meji láti Akasia, lọ sí Jẹriko, ó ní, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá jùlọ, ìlú Jẹriko.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì dé sí ilé aṣẹ́wó kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rahabu.


Wọ́n pada tọ Joṣua wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Má wulẹ̀ jẹ́ kí gbogbo àwọn eniyan lọ gbógun ti ìlú Ai, yan àwọn eniyan bí ẹgbaa (2,000) tabi ẹgbẹẹdogun (3,000) kí wọ́n lọ gbógun ti ìlú náà. Má wulẹ̀ lọ dààmú gbogbo àwọn eniyan lásán, nítorí pé àwọn ará Ai kò pọ̀ rárá.”


Àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Wọ́n ní ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ẹgbaata (6,000) ẹlẹ́ṣin, àwọn ọmọ ogun wọn sì pọ̀ bí eṣú. Wọ́n lọ sí Mikimaṣi ní ìhà ìlà oòrùn Betafeni, wọ́n pàgọ́ wọn sibẹ.


Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe ṣẹgun fún àwọn ọmọ Israẹli ní ọjọ́ náà, wọ́n sì ja ogun náà kọjá Betafeni.


Ó fi ranṣẹ sí àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli, ati àwọn tí wọ́n wà ní Ramoti ti Nẹgẹbu, ati Jatiri;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan