Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 7:12 - Yoruba Bible

12 Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn nítorí pé, wọ́n ti di ẹni ìparun. N kò ní wà pẹlu yín mọ́, àfi bí ẹ bá run àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ tí ó wà láàrin yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Nitorina ni awọn ọmọ Israeli kò ṣe le duro niwaju awọn ọtá wọn, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọtá wọn, nitoriti nwọn di ẹni ifibu: emi ki yio wà pẹlu nyin mọ́, bikoṣepe ẹnyin pa ohun ìyasọtọ run kuro lãrin nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ìdí nì èyí tí àwọn ará Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n yí ẹ̀yìn wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀tá a wọn nítorí pé àwọn gan an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pa ohun ìyàsọ́tọ̀ run kúrò ní àárín yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 7:12
21 Iomraidhean Croise  

O ti mú kí á sá fún àwọn ọ̀tá wa lójú ogun; àwọn tí ó kórìíra wa sì fi ẹrù wa ṣe ìkógun.


Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀? Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.


Àwọn eniyan burúkú a máa sá, nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé wọn, ṣugbọn olódodo a máa láyà bíi kinniun.


Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó fa ìyapa láàrin ẹ̀yin ati Ọlọrun yín, àìdára yín ni ó mú kí ó fojú pamọ́ fun yín, tí kò fi gbọ́ ẹ̀bẹ̀ yín.


Bí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọnyi, tabi wolii kan, tabi alufaa kan, bá bi ọ́ léèrè pé, “Kí ni iṣẹ́ tí OLUWA rán?” Wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin gan-an ni ẹ jẹ́ ẹrù. OLUWA sì ní òun óo gbé yín sọnù.”


Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ tí mò ń ṣe fun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi pẹlu yín óo pínyà, n óo sì sọ Jerusalẹmu di ahoro, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé ibẹ̀ mọ́.”


Bí wọ́n bá tilẹ̀ bímọ, n óo pa wọ́n tí kò ní ku ẹyọ kan. Bí mo bá kọ̀ wọ́n sílẹ̀, wọ́n gbé!”


Mímọ́ ni ojú rẹ, o kò lè wo ibi o kò lè gba ohun tí kò tọ́. Kí ló wá dé tí o fi ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀, tí o sì dákẹ́, tí ò ń wo àwọn ẹni ibi níran tí wọn ń run àwọn tí wọ́n ṣe olódodo jù wọ́n lọ.


Nígbà tí Mose sọ ohun tí OLUWA sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n káàánú gidigidi.


Ẹ má lọ nítorí OLUWA kò ní wà pẹlu yín, àwọn ọ̀tá yín yóo sì ṣẹgun yín.


Ẹ óo kú nígbà tí ẹ bá ń bá àwọn ará Amaleki ati Kenaani jagun. OLUWA kò ní wà pẹlu yín nítorí pé ẹ ti ṣe àìgbọràn sí i.”


Àwọn ará Amaleki ati Kenaani tí ń gbé ibẹ̀ bá wọn jagun, wọ́n ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì lé wọn títí dé Horima.


Ẹ kò sì gbọdọ̀ mú ohun ìríra wọ ilé yín, kí ẹ má baà di ẹni ìfibú gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ohun ìfibú. Ẹ níláti kórìíra wọn, kí ẹ sì yàgò fún wọn, nítorí ohun ìfibú ni wọ́n.


Ẹ yẹra fún ohunkohun tí OLUWA ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ má baà di ẹni ègún nípa mímú ohun tí OLUWA ti yà sọ́tọ̀, kí ẹ má baà sọ àgọ́ Israẹli di ohun ìparun, kí ẹ sì kó ìyọnu bá a.


Ó wí fún un pé, “Samsoni! Àwọn ará Filistia ti dé.” Samsoni bá jí láti ojú oorun, ó ní, “N óo lọ bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, n óo sì gba ara mi lọ́wọ́ wọn.” Kò mọ̀ pé OLUWA ti fi òun sílẹ̀.


Inú bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó bá fi wọ́n lé àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà kan lọ́wọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jí wọn ní nǹkan kó. OLUWA tún fi wọ́n lé gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó wà ní àyíká wọn lọ́wọ́, apá wọn kò sì ká àwọn ọ̀tá wọn mọ́.


Nígbà tí Angẹli OLUWA sọ ọ̀rọ̀ yìí fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.


Saulu bá pe gbogbo olórí àwọn eniyan náà jọ, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí á wádìí ohun tí ó fa ẹ̀ṣẹ̀ òní.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan