Joṣua 7:11 - Yoruba Bible11 Israẹli ti ṣẹ̀, wọ́n ti rú òfin mi. Wọ́n ti mú ninu àwọn ohun tí a yà sọ́tọ̀, wọ́n ti jalè, wọ́n ti purọ́, wọn sì ti fi ohun tí wọ́n jí pamọ́ sábẹ́ àwọn ohun ìní wọn. Faic an caibideilBibeli Mimọ11 Israeli ti dẹ̀ṣẹ, nwọn si ti bà majẹmu mi jẹ́ ti mo palaṣẹ fun wọn: ani nwọn ti mú ninu ohun ìyasọtọ nì; nwọn si jale, nwọn si ṣe agabagebe pẹlu, ani nwọn si fi i sinu ẹrù wọn. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní11 Israẹli ti ṣẹ̀; Wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, Wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn. Faic an caibideil |
“Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì dẹ́ṣẹ̀ nípa pé kò san àwọn nǹkan tíí ṣe ti OLUWA fún OLUWA, ohun tí yóo mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi fún OLUWA ni: àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n, láti inú agbo aguntan rẹ̀, ìwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn fadaka ninu ilé OLUWA ni wọn yóo lò láti fi díyelé àgbò náà; ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ni.