Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 7:1 - Yoruba Bible

1 Àwọn ọmọ Israẹli dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nítorí pé ẹnìkan mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Akani ọmọ Karimi, ọmọ Sabidi, ọmọ Sera, láti inú ẹ̀yà Juda, mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀, inú sì bí OLUWA gidigidi sí àwọn ọmọ Israẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 ṢUGBỌN awọn ọmọ Israeli dẹ́ṣẹ kan niti ohun ìyasọtọ: nitoriti Akani, ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀ya Juda, mú ninu ohun ìyasọtọ: ibinu OLUWA si rú si awọn ọmọ Israeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀yà Juda, mú nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ará Israẹli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 7:1
19 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Jakọbu wá kó gbogbo ohun ìní àwọn ará ìlú náà nítorí pé wọ́n ba arabinrin wọn jẹ́.


Inú tún bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì ti Dafidi láti kó ìyọnu bá wọn. OLUWA wí fún un pé, lọ ka àwọn ọmọ Israẹli ati ti Juda.


Nígbà tí wọ́n dé orí òkè tí Eliṣa ń gbé, Gehasi gba àwọn ẹrù náà lórí wọn, ó gbé wọn sinu ilé, ó sì dá àwọn iranṣẹ Naamani pada.


Inú Ọlọrun kò dùn sí ọ̀rọ̀ náà, nítorí náà ó jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà.


Wọ́n kọ ilé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì ń sin oriṣa Aṣera ati àwọn ère mìíràn. Nítorí ìwà burúkú yìí, inú bí OLUWA sí Juda ati Jerusalẹmu.


“Ọlọrun mi, ojú tì mí tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè gbójú sókè níwájú rẹ. Ìwà burúkú wa pọ̀ pupọ níwájú rẹ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ní ìpele ìpele, sì ga títí kan ọ̀run.


Àwọn eniyan burúkú bíì rẹ, ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lè pa lára, àwọn ọmọ eniyan ni òdodo rẹ sì lè jẹ́ anfaani fún.


Ọgbọ́n dára ju ohun ìjà ogun lọ, ṣugbọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kanṣoṣo a máa ba nǹkan ribiribi jẹ́.


Olódodo ni ọ́, OLUWA, ṣugbọn lónìí yìí ojú ti gbogbo àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu, ati gbogbo Israẹli; ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn, níbi gbogbo tí o fọ́n wọn káàkiri sí nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí ọ.


Mose sọ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ meji, Eleasari ati Itamari pé, “Ẹ má ṣe fi irun yín sílẹ̀ játijàti, ẹ má sì ṣe fa aṣọ yín ya (láti fihàn pé ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀), kí ẹ má baà kú, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí gbogbo eniyan. Ṣugbọn gbogbo ilé Israẹli, àwọn eniyan yín, lè ṣọ̀fọ̀ iná tí OLUWA fi jó yín.


Wọ́n bá dámọ̀ràn láàrin ara wọn, wọ́n ní “Ẹ jẹ́ kí á ṣẹ́ gègé, kí á lè mọ ẹni tí ó fà á, tí nǹkan burúkú yìí fi dé bá wa.” Wọ́n ṣẹ́ gègé, gègé bá mú Jona.


“Gbogbo ìjọ eniyan Ọlọrun ní kí á bèèrè lọ́wọ́ yín pé, irú ìwà ọ̀dàlẹ̀ wo ni ẹ hù sí OLUWA Ọlọrun Israẹli yìí? Ẹ ti yára pada lẹ́yìn OLUWA, ẹ kò sì tẹ̀lé e mọ́, nítorí pé ẹ ti ṣe oríkunkun sí OLUWA nípa títẹ́ pẹpẹ fún ara yín.


Kí ni ìbáà ṣẹlẹ̀, tí ẹ fi níláti yára yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ sì ni bí ẹ bá ṣe oríkunkun sí OLUWA lónìí, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni yóo bínú sí lọ́la.


Ṣebí ìwà ọ̀dàlẹ̀ báyìí náà ni Akani ọmọ Sera hù nígbà tí ó kọ̀, tí kò tẹ̀lé àṣẹ tí OLUWA pa nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ OLUWA, ṣebí gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli ni OLUWA bínú sí? Àbí òun nìkan ni ó ṣègbé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan