Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 6:4 - Yoruba Bible

4 Kí àwọn alufaa meje mú fèrè ogun kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu. Ní ọjọ́ keje ẹ óo yípo ìlú náà nígbà meje, àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè ogun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Alufa meje yio gbé ipè jubeli meje niwaju apoti na: ni ijọ́ keje ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃meje, awọn alufa yio si fọn ipè wọnni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Jẹ́ kí àwọn àlùfáà méje gbé fèrè ìwo àgbò ní iwájú àpótí ẹ̀rí. Ní ọjọ́ keje, Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, pẹ̀lú àwọn àlùfáà tí ń fọn fèrè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 6:4
33 Iomraidhean Croise  

Ó súre fún ọjọ́ keje yìí, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ọjọ́ náà ni ó sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe bọ̀.


Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ wo apá ìhà òkun. Iranṣẹ náà lọ, ó sì pada wá, ó ní, òun kò rí nǹkankan. Elija sọ fún un pé, “Tún lọ ní ìgbà meje.”


Eliṣa rán iranṣẹ kan kí ó sọ fún un pé kí ó lọ wẹ ara rẹ̀ ninu odò Jọdani ní ìgbà meje, yóo sì rí ìwòsàn.


Naamani bá lọ sí odò Jọdani, ó wẹ̀ ní ìgbà meje gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti pàṣẹ fún un, ó rí ìwòsàn, ara rẹ̀ sì jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde.


Ọlọrun wà pẹlu wa, òun fúnrarẹ̀ ni aṣaaju wa. Àwọn alufaa rẹ̀ wà níhìn-ín láti fun fèrè láti pè wá kí á gbógun tì yín. Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ má ṣe bá OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín jà, nítorí ẹ kò ní borí.”


Ẹ kò ní jagun rárá, ẹ sá dúró ní ààyè yín, kí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo sì rí bí OLUWA yóo ti gba ẹ̀yin ará Juda ati Jerusalẹmu là. Ẹ má fòyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì, Ẹ lọ kò wọ́n lójú lọ́la, OLUWA yóo wà pẹlu yín.”


Ni àwọn ọmọ Lefi láti inú ìdílé Kohati ati ti Kora bá dìde, wọ́n gbóhùn sókè, wọ́n sì yin OLUWA Ọlọrun Israẹli.


Nígbà tí Jehoṣafati bá àwọn eniyan rẹ̀ jíròrò tán, ó yan àwọn tí wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA; tí wọn yóo wọ aṣọ mímọ́, tí wọn yóo sì máa yìn ín bí wọn yóo ti máa lọ níwájú ogun, wọn yóo máa kọrin pé, “Ẹ yin OLUWA! Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ dúró laelae.”


Nítorí náà, mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje lọ sí ọ̀dọ̀ Jobu kí o rú ẹbọ sísun fún ara rẹ; Jobu iranṣẹ mi yóo sì gbadura fún ọ, n óo gbọ́ adura rẹ̀, n kò sì ní ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ. Nítorí o kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi gẹ́gẹ́ bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.”


Ní ọjọ́ náà, a óo fun fèrè ogun ńlá, àwọn tí ó ti sọnù sí ilẹ̀ Asiria ati àwọn tí a lé lọ sí ilẹ̀ Ijipti yóo wá sin OLUWA lórí òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.


Yóo ti ìka ọ̀tún rẹ̀ bọ òróró tí ó wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo sì fi ìka rẹ̀ wọ́n òróró náà níwájú OLUWA ní ìgbà meje.


Yóo ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, yóo sì wọ́n ọn sílẹ̀ nígbà meje níwájú OLUWA, níwájú aṣọ ìkélé tí ó wà ní ibi mímọ́.


Ó bi mí pé kí ni mo rí. Mo dáhùn pé, “Mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà, àwo kan sì wà lórí rẹ̀. Fìtílà meje wà lórí ọ̀pá náà, fìtílà kọ̀ọ̀kan sì ní òwú fìtílà meje.


Angẹli náà sọ fún mi pé, “Iṣẹ́ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun rán sí Serubabeli ni pé, ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bíkòṣe nípa ẹ̀mí mi.


Balaamu sọ fún Balaki pé, “Tẹ́ pẹpẹ meje sí ibí yìí fún mi kí o sì pèsè akọ mààlúù meje ati àgbò meje.”


Àwọn alufaa meje tí wọ́n mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA kọjá siwaju, wọ́n sì ń fọn fèrè ogun wọn lemọ́lemọ́. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun wà níwájú wọn, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu OLUWA. Àwọn tí ń fọn fèrè ogun ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́.


Ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ yóo rìn yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan lojumọ fún ọjọ́ mẹfa.


Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè ogun náà gidigidi, tí ẹ sì gbọ́ ìró rẹ̀, kí gbogbo àwọn eniyan hó yèè! Ògiri ìlú náà yóo sì wó. Kí olukuluku àwọn ọmọ ogun wọ inú ìlú náà lọ tààrà.”


Àṣírí ìràwọ̀ meje tí o rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ati ti ọ̀pá fìtílà wúrà meje nìyí: ìràwọ̀ meje ni àwọn angẹli ìjọ meje. Ọ̀pá fìtílà meje ni àwọn ìjọ meje.


Èmi Johanu ni mo ranṣẹ sí ìjọ meje tí ó wà ní agbègbè Esia. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia wà pẹlu yín láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti wà, tí ó ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, ati láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí meje tí wọ́n wà níwájú ìtẹ́ rẹ̀;


Ó wá bú ramúramù bíi kinniun. Nígbà tí ó bú báyìí tán, ààrá meje sán.


Mo tún rí ohun abàmì mìíràn ní ọ̀run, ohun ńlá ati ohun ìyanu: àwọn angẹli meje tí àjàkálẹ̀ àrùn meje ti ìkẹyìn wà ní ìkáwọ́ wọn, nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibinu Ọlọrun wá sí òpin.


Ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè náà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje náà ní àwo wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan, àwọn àwo wúrà yìí kún fún ibinu Ọlọrun, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae.


Mo gbọ́ ohùn líle kan láti inú Tẹmpili tí ó sọ fún àwọn angẹli meje náà pé, “Ẹ lọ da àwọn àwo meje tí ó kún fún ibinu Ọlọrun sinu ayé.”


Lẹ́yìn náà, mo rí ìwé kan ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́: wọ́n kọ nǹkan sí i ninu ati lóde, wọ́n sì fi èdìdì meje dì í.


Mo bá rí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó dúró láàrin ìtẹ́ náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà yí i ká. Ọ̀dọ́ Aguntan náà dàbí ẹni pé wọ́n ti pa á. Ìwo meje ni ó ní ati ojú meje. Àwọn ojú meje yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje tí Ọlọrun rán sí gbogbo orílẹ̀ ayé.


Mo bá rí àwọn angẹli meje tí wọn máa ń dúró níwájú Ọlọrun, a fún wọn ní kàkàkí meje.


Àwọn angẹli meje tí wọ́n mú kàkàkí meje lọ́wọ́ bá múra láti fun kàkàkí wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan