Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 6:1 - Yoruba Bible

1 Wọ́n ti ìlẹ̀kùn odi Jẹriko ninu ati lóde, nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnikẹ́ni kò lè jáde, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè wọlé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 (NJẸ a há Jeriko mọ́ gága nitori awọn ọmọ Israeli: ẹnikẹni kò jade, ẹnikẹni kò si wọle.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Wàyí o, a ti há Jeriko mọ́lé gágá nítorí àwọn ọmọ Israẹli, ẹnikẹ́ni kò jáde, ẹnikẹ́ni kò sì wọlé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 6:1
12 Iomraidhean Croise  

Ìtìjú bá wọn tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò lè pada sílé. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ranṣẹ sí wọn pé kí wọ́n dúró ní Jẹriko títí tí irùngbọ̀n wọn yóo fi hù, kí wọ́n tó máa pada bọ̀.


Ṣugbọn ní ọdún kan, Hoṣea ranṣẹ sí So, ọba Ijipti pé, kí ó ran òun lọ́wọ́, kò sì san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Asiria mọ́. Nígbà tí Ṣalimaneseri gbọ́, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ju Hoṣea sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n.


Elija tún sọ fún Eliṣa pé, “Dúró níhìn-ín, nítorí pé OLUWA rán mi sí Jẹriko.” Eliṣa dáhùn pé, “Bí OLUWA ti wà láàyè, tí ìwọ náà sì wà láàyè, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà wọ́n jọ lọ sí Jẹriko.


Bí OLUWA kò bá kọ́ ilé, asán ni wahala àwọn tí ń kọ́ ọ. Bí OLUWA kò bá ṣọ́ ìlú, asán ni àìsùn àwọn aṣọ́de.


Lẹ́yìn náà, ní ìsàlẹ̀, láti Janoa, lọ sí Atarotu ati Naara. Ó lọ títí dé Jẹriko, ó sì pin sí odò Jọdani.


Àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ náà ni: Jẹriko, Beti Hogila, Emeki Kesisi;


Lẹ́yìn náà, Joṣua ọmọ Nuni rán amí meji láti Akasia, lọ sí Jẹriko, ó ní, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá jùlọ, ìlú Jẹriko.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì dé sí ilé aṣẹ́wó kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rahabu.


Wọ́n sọ fún Joṣua pé, “Láìṣe àní àní, OLUWA ti fi ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́, ìdààmú ọkàn sì ti bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà nítorí wa.”


Àwọn tí ọba rán bá bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọkunrin náà lọ ní ọ̀nà odò Jọdani, títí dé ibi tí ọ̀nà ti rékọjá odò náà, bí àwọn tí ọba rán ti jáde ní ìlú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti ìlẹ̀kùn odi ìlú náà.


Balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA dá Joṣua lóhùn pé, “Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí o dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀.


OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti fi Jẹriko lé ọ lọ́wọ́ ati ọba wọn ati àwọn akikanju wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan