Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 5:9 - Yoruba Bible

9 OLUWA wí fún Joṣua pé, “Lónìí yìí ni mo mú ẹ̀gàn àwọn ará Ijipti kúrò lára yín.” Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Giligali títí di òní olónìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni ni mo yi ẹ̀gan Egipti kuro lori nyin. Nitorina li a ṣe npè orukọ ibẹ̀ ni Gilgali titi o fi di oni yi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Nígbà náà ní Olúwa wí fún Joṣua pé, “Ní òní ni mo yí ẹ̀gàn Ejibiti kúrò ní orí yín.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Gilgali títí ó fi di òní yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 5:9
21 Iomraidhean Croise  

Wọ́n wí fún wọn pé, “Ìtìjú gbáà ni ó jẹ́, pé kí a fi ọmọbinrin wa fún ẹni tí kò kọlà abẹ́, a kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá.


Nígbà tí ọba ń pada bọ̀, àwọn eniyan Juda wá sí Giligali láti pàdé rẹ̀ ati láti mú un kọjá odò Jọdani.


bákan náà ni láti Betigiligali ati láti ẹkùn Geba, ati Asimafeti, nítorí pé àwọn akọrin kọ́ ìletò fún ara wọn ní agbègbè Jerusalẹmu.


Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò, nítorí pé ìlànà rẹ dára.


Ó ní, “Ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo fìyà jẹ àwọn tí a kọ nílà, ṣugbọn tí wọn ń ṣe bí aláìkọlà,


Wọ́n lọ ṣe aṣẹ́wó ní ilẹ̀ Ijipti nígbà tí wọ́n jẹ́ ọmọge. Àwọn kan fọwọ́ fún wọn lọ́mú, wọ́n fọwọ́ pa orí ọmú wọn nígbà tí wọn kò tíì mọ ọkunrin.


Kò kọ ìwà àgbèrè rẹ̀ tí ó ń hù nígbà tí ó ti wà ní ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀. Nígbà èwe rẹ̀, àwọn ọkunrin bá a lòpọ̀, wọ́n fọwọ́ pa á lọ́mú, wọ́n sì tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn lára rẹ̀.


“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ìwọ Israẹli, má kó ẹ̀bi bá Juda. Má wọ Giligali lọ bọ̀rìṣà, má sì gòkè lọ sí Betafeni, má sì lọ búra níbẹ̀ pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ.’


“Mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, kí gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ nígbà tí ó ṣépè gbé ọwọ́ lé e lórí, kí gbogbo ìjọ eniyan sì sọ ọ́ ní òkúta pa.


ẹ má lọ sí Bẹtẹli, ẹ má sì wọ Giligali, tabi kí ẹ kọjá lọ sí Beeriṣeba; nítorí a óo kó Giligali lọ sí oko ẹrú, Bẹtẹli yóo sì di asán.”


Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ ranti ète tí Balaki, ọba Moabu pa si yín, ati ìdáhùn tí Balaamu, ọmọ Beori, fún un. Ẹ ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ìrìn àjò yín láti Ṣitimu dé Giligali, kí ẹ lè mọ iṣẹ́ ìgbàlà tí OLUWA ṣe.”


OLUWA ní: “Mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àbùkù tí àwọn ará Moabu ń sọ ati bí àwọn ará Amoni tí ń fọ́nnu, bí wọn tí ń fi àwọn eniyan mi ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ń lérí pé àwọn yóo gba ilẹ̀ wọn. Nítorí náà bí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ti wà láàyè,


“Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú. Ẹ kó gbogbo oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò ati ní Ijipti dànù, kí ẹ sì máa sin OLUWA.


Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kinni ni àwọn eniyan náà gun òkè odò Jọdani. Wọ́n pàgọ́ sí Giligali ní ìhà ìlà oòrùn Jẹriko.


Nígbà tí àwọn eniyan náà kọ ilà abẹ́ tán, olukuluku wà ní ààyè rẹ̀ ninu àgọ́ títí egbò wọn fi jinná.


Jonatani bá pe ọdọmọkunrin tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó ní, “Jẹ́ kí á rékọjá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Filistia, àwọn aláìkọlà wọnyi, bóyá OLUWA a jẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Bí OLUWA bá fẹ́ ran eniyan lọ́wọ́, kò sí ohun tí ó lè dí i lọ́wọ́, kì báà jẹ́ pé eniyan pọ̀ ni, tabi wọn kò pọ̀.”


Dafidi bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọkunrin náà pé, “Kí ni ọba ṣe ìlérí pé òun ó fún ẹni tí ó bá pa Filistini yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Israẹli? Ta ni aláìkọlà Filistini yìí tí ń pẹ̀gàn àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè?”


Èmi iranṣẹ rẹ yìí ti pa àwọn kinniun ati àwọn ẹranko beari rí, aláìkọlà Filistini yìí yóo sì dàbí ọ̀kan ninu wọn, nítorí pé, ó ti pe àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè níjà.


Lọdọọdun níí máa ń lọ yípo Bẹtẹli, Giligali, ati Misipa, láti ṣe ìdájọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan