Joṣua 5:7 - Yoruba Bible7 Nítorí náà, àwọn ọmọ wọn tí OLUWA gbé dìde dípò wọn ni Joṣua kọ ilà abẹ́ fún, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò kọ wọ́n ní ilà ní ojú ọ̀nà. Faic an caibideilBibeli Mimọ7 Ati awọn ọmọ wọn, ti o gbé dide ni ipò wọn, awọn ni Joṣua kọnilà: nitoriti nwọn wà li alaikọlà, nitoriti a kò kọ wọn nilà li ọ̀na. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 Bẹ́ẹ̀ ni ó gbé àwọn ọmọ wọn dìde dípò wọn, àwọn wọ̀nyí sì ni Joṣua kọ ní ilà. Wọ́n wà ní aláìkọlà nítorí a kò tí ì kọ wọ́n ní ilà ní ojú ọ̀nà. Faic an caibideil |
Nítorí pé ogoji ọdún ni àwọn ọmọ Israẹli fi ń rìn kiri láàrin aṣálẹ̀, títí tí àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti Ijipti fi parun tán, nítorí wọn kò gbọ́ ti OLUWA wọn. OLUWA sì ti búra pé, òun kò ní jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀ tí òun ti búra láti fún àwọn baba wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.