Joṣua 5:5 - Yoruba Bible5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n kọ ilà abẹ́, ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bí lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní ilẹ̀ Ijipti kò kọ ilà. Faic an caibideilBibeli Mimọ5 Nitori gbogbo awọn enia ti o jade ti ibẹ̀ wà, a kọ wọn nilà: ṣugbọn gbogbo awọn enia ti a bi li aginjù li ọ̀na, bi nwọn ti jade kuro ni Egipti, awọn ni a kò kọnilà. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, gbogbo àwọn ọkùnrin tó jáde láti Ejibiti ni a ti kọ ní ilà, síbẹ̀ gbogbo ènìyàn tí a bí nínú aginjù lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní Ejibiti ni wọn kò kọ ní ilà. Faic an caibideil |
Nítorí pé ogoji ọdún ni àwọn ọmọ Israẹli fi ń rìn kiri láàrin aṣálẹ̀, títí tí àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti Ijipti fi parun tán, nítorí wọn kò gbọ́ ti OLUWA wọn. OLUWA sì ti búra pé, òun kò ní jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀ tí òun ti búra láti fún àwọn baba wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.