Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 5:4 - Yoruba Bible

4 Ìdí tí Joṣua fi kọ ilà abẹ́ fún wọn ni pé, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ti kú lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde láti ilẹ̀ Ijipti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Idí rẹ̀ li eyi ti Joṣua fi kọ wọn nilà: gbogbo awọn enia ti o ti Egipti jade wá, ti o ṣe ọkunrin, ani gbogbo awọn ọmọ-ogun, nwọn kú li aginjù, li ọ̀na, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni Egipti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Wàyí o, ìdí tí Joṣua fi kọ wọ́n nílà nìyìí: Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó ti Ejibiti jáde wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun kú ní aginjù ní ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 5:4
8 Iomraidhean Croise  

àwọn eniyan wọnyi, tí wọ́n ti rí ògo mi ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe ní Ijipti ati ninu aṣálẹ̀, ṣugbọn tí wọ́n ti dán mi wò nígbà mẹ́wàá, tí wọ́n sì ṣàìgbọràn sí mi,


Ṣugbọn sibẹ inú Ọlọrun kò dùn sí ọpọlọpọ ninu wọn, nítorí ọpọlọpọ wọn ni wọ́n kú dànù káàkiri ninu aṣálẹ̀.


Lẹ́yìn ọdún mejidinlogoji gbáko tí a ti kúrò ní Kadeṣi Banea, ni a tó kọjá odò Seredi, títí tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun ún jà ninu ìran náà fi run tán patapata, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti búra pé yóo rí.


“Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun-ún jà ti kú tán láàrin àwọn ọmọ Israẹli,


Joṣua bá fi akọ òkúta ṣe abẹ, ó fi kọ ilà abẹ́ fún gbogbo ọkunrin Israẹli ní Gibeati Haaraloti.


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n kọ ilà abẹ́, ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bí lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní ilẹ̀ Ijipti kò kọ ilà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan