Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 5:10 - Yoruba Bible

10 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí Giligali, wọ́n ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù náà, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Awọn ọmọ Israeli si dó ni Gilgali; nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla oṣù li ọjọ́ alẹ, ni pẹtẹlẹ̀ Jeriko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù náà (oṣù kẹrin) nígbà tí wọ́n pàgọ́ ní Gilgali ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko, àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ọdún Àjọ ìrékọjá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 5:10
14 Iomraidhean Croise  

N óo dúró ní ibi tí wọ́n ń gbà la odò kọjá ní ijù níhìn-ín, títí tí n óo fi rí oníṣẹ́ rẹ.”


Bí ẹ ó ṣe jẹ ẹ́ nìyí: ẹ di àmùrè yín mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín, ẹ wọ bàtà yín, ẹ mú ọ̀pá yín lọ́wọ́; ìkánjú ni kí ẹ fi jẹ ẹ́, nítorí pé oúnjẹ ìrékọjá fún OLUWA ni.


Láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni yìí títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọkanlelogun oṣù náà, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ.


Wọ́n óo so ẹran wọn mọ́lẹ̀ títí di ọjọ́ kẹrinla oṣù yìí. Nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, gbogbo ìjọ eniyan Israẹli yóo pa ẹran wọn.


Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lé wọn, wọ́n bá Sedekaya ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; wọ́n mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Nebukadinesari ọba Babiloni ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati, ó sì dá Sedekaya lẹ́jọ́.


“Nítorí náà, ìwọ ọmọ eniyan, di ẹrù rẹ bíi ti ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn, kí o sì jáde ní ìlú lọ́sàn-án gangan níṣojú wọn. Lọ láti ilé rẹ sí ibòmíràn bí ẹni tí ń lọ sí ìgbèkùn. Bóyá yóo yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.


“Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ni kí ẹ máa ṣe àjọ ìrékọjá OLUWA.


Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ ranti ète tí Balaki, ọba Moabu pa si yín, ati ìdáhùn tí Balaamu, ọmọ Beori, fún un. Ẹ ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ìrìn àjò yín láti Ṣitimu dé Giligali, kí ẹ lè mọ iṣẹ́ ìgbàlà tí OLUWA ṣe.”


Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kinni ni àwọn eniyan náà gun òkè odò Jọdani. Wọ́n pàgọ́ sí Giligali ní ìhà ìlà oòrùn Jẹriko.


Òwúrọ̀ ọjọ́ keji lẹ́yìn àjọ ìrékọjá ni ìgbà kinni tí wọ́n fi ẹnu kàn ninu èso ilẹ̀ náà, wọ́n jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ati ọkà gbígbẹ.


Wọ́n tọ Joṣua lọ ninu àgọ́ tí ó wà ní Giligali, wọ́n wí fún òun ati àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ọ̀nà jíjìn ni a ti wá, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á dá majẹmu.”


Lọdọọdun níí máa ń lọ yípo Bẹtẹli, Giligali, ati Misipa, láti ṣe ìdájọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan