Joṣua 5:1 - Yoruba Bible1 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Amori, tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, ati gbogbo ọba àwọn ará ilẹ̀ Kenaani, tí wọ́n wà ní etí Òkun gbọ́ pé OLUWA mú kí odò Jọdani gbẹ nítorí àwọn ọmọ Israẹli, títí tí wọ́n fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, àyà wọn já, ìdààmú sì bá wọn, nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Faic an caibideilBibeli Mimọ1 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba Amori, ti o wà ni ìha keji Jordani ni ìwọ-õrùn, ati gbogbo awọn ọba Kenaani ti mbẹ leti okun, gbọ́ pe OLUWA ti mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa fi là a kọja, ni àiya wọn já, bẹ̃li ẹmi kò sí ninu wọn mọ́, nitori awọn ọmọ Israeli. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní1 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba Amori ti ìlà-oòrùn Jordani àti gbogbo àwọn ọba Kenaani tí ń bẹ létí Òkun gbọ́ bí Olúwa ti mú Jordani gbẹ ní iwájú àwọn ọmọ Israẹli títí ti a fi kọjá, ọkàn wọn pami, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ìgboyà mọ́ láti dojúkọ àwọn ọmọ Israẹli. Faic an caibideil |
Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n ní: “Àwọn ọmọ Israẹli pẹlu àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi kò ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò ninu ìwà ìríra àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Perisi ati àwọn ará Jebusi, ti àwọn ará Amoni ati àwọn ará Moabu, àwọn ará Ijipti, ati àwọn ará Amori.