Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 4:9 - Yoruba Bible

9 Joṣua to òkúta mejila mìíràn jọ láàrin odò Jọdani lọ́gangan ibi tí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu dúró sí; àwọn òkúta náà wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Joṣua si tò okuta mejila jọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na gbé duro: nwọn si mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Joṣua sì to òkúta méjìlá náà sí àárín odò Jordani fún ìrántí ní ọ̀kánkán ibi tí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí dúró sí. Wọ́n sì wà níbẹ̀ di òní yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 4:9
16 Iomraidhean Croise  

Ó sọ kànga náà ní Ṣeba. Ìdí nìyí tí orúkọ ìlú náà fi ń jẹ́ Beeriṣeba títí di òní yìí.


Jakọbu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí nàró gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀n, ó sì da òróró sórí rẹ̀.


Àwọn ará Beeroti ti sá lọ sí Gitaimu, ibẹ̀ ni wọ́n sì ń gbé títí di òní olónìí.


Ó kó òkúta mejila jọ, òkúta kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Jakọbu, ẹni tí OLUWA sọ fún pé, “Israẹli ni orúkọ rẹ yóo máa jẹ́.”


Àwọn ọ̀pá náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi lè rí orí wọn láti ibi mímọ́ jùlọ, ṣugbọn wọn kò lè rí wọn láti ìta. Wọ́n wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.


OLUWA wí fún Mose pé, “Gun orí òkè tọ̀ mí wá, kí o dúró sibẹ, n óo sì kó wàláà tí wọ́n fi òkúta ṣe fún ọ, tí mo kọ àwọn òfin ati ìlànà sí, fún ìtọ́ni àwọn eniyan yìí.”


Oríṣìí òkúta mejila ni yóo wà, orúkọ wọn yóo dàbí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli; wọn yóo dàbí èdìdì, wọn yóo sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejila sí ara àwọn òkúta mejeejila, òkúta kan fún ẹ̀yà kan.


Ìdí nìyí ti a fi ń pe ilẹ̀ náà ní, “Ilẹ̀ ẹ̀jẹ̀” títí di òní olónìí.


Àwọn ọmọ-ogun náà bá gba owó tí wọ́n fún wọn, wọ́n ṣe bí wọ́n ti kọ́ wọn. Èyí náà sì ni ìtàn tí àwọn Juu ń sọ káàkiri títí di òní olónìí.


OLUWA sin ín sí àfonífojì ilẹ̀ Moabu tí ó dojú kọ Betipeori, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò mọ ibojì rẹ̀ títí di òní olónìí.


Ó kọ ọ̀rọ̀ náà sinu ìwé òfin Ọlọrun, ó gbé òkúta ńlá kan, ó sì fi gúnlẹ̀ lábẹ́ igi Oaku, ní ibi mímọ́ OLUWA,


Nítorí pé àwọn alufaa tí ó gbé Àpótí Majẹmu OLUWA dúró láàrin odò Jọdani, títí tí àwọn eniyan náà fi ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé kí Joṣua sọ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún un.


Ọkunrin náà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hiti, ó tẹ ìlú kan dó, ó sì sọ ọ́ ní Lusi. Orúkọ náà ni wọ́n ń pe ìlú náà títí di òní olónìí.


Láti ọjọ́ náà ni ó ti sọ ọ́ di òfin ati ìlànà ní Israẹli, títí di òní olónìí.


Samuẹli gbé òkúta kan, ó rì í mọ́lẹ̀ láàrin Misipa ati Ṣeni, ó sì sọ ibẹ̀ ni Ebeneseri, ó ní, “OLUWA ràn wá lọ́wọ́ títí dé ìhín yìí.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan