Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 4:8 - Yoruba Bible

8 Àwọn ọkunrin náà ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Joṣua pa fún wọn. Wọ́n gbé òkúta mejila láti inú odò Jọdani, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà tí ó wà ninu àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Joṣua. Wọ́n gbé wọn lọ́wọ́ lọ sí ibi tí wọ́n sùn ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì tò wọ́n jọ sibẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi Joṣua ti paṣẹ, nwọn si gbé okuta mejila lati inu ãrin Jordani lọ, bi OLUWA ti wi fun Joṣua, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli; nwọn si rù wọn kọja pẹlu wọn lọ si ibùsun, nwọn si gbé wọn kalẹ nibẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bí Joṣua ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, bí Olúwa ti sọ fún Joṣua; wọ́n sì rù wọ́n kọjá lọ sí ibùdó, ní ibi tí wọ́n ti gbé wọn kalẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 4:8
6 Iomraidhean Croise  

Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose ati Aaroni.


Mose bá kọ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ kutukutu, ó dìde, ó tẹ́ pẹpẹ kan sí ìsàlẹ̀ òkè náà, ó ri ọ̀wọ̀n mejila mọ́lẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan.


Joṣua bá to àwọn òkúta mejila tí wọ́n kó jáde láti inú odò Jọdani kalẹ̀ ní Giligali.


Joṣua to òkúta mejila mìíràn jọ láàrin odò Jọdani lọ́gangan ibi tí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu dúró sí; àwọn òkúta náà wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan