Joṣua 4:7 - Yoruba Bible7 Nígbà náà, ẹ óo dá wọn lóhùn pé omi odò Jọdani pín sí meji níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA nígbà tí wọn gbé e kọjá odò náà. Nítorí náà, àwọn òkúta wọnyi yóo jẹ́ ohun ìrántí ayérayé fún àwọn ọmọ Israẹli.” Faic an caibideilBibeli Mimọ7 Nigbana li ẹnyin o da wọn lohùn pe, Nitori a ke omi Jordani niwaju apoti majẹmu OLUWA; nigbati o rekọja Jordani, a ke omi Jordani kuro: okuta wọnyi yio si jasi iranti fun awọn ọmọ Israeli lailai. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jordani kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí a rékọjá a Jordani, a gé omi Jordani kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli láéláé.” Faic an caibideil |
“Ati ẹni tí ó pa mààlúù rúbọ, ati ẹni tí ó pa eniyan; kò sí ìyàtọ̀. Ẹni tí ó fi ọ̀dọ́ aguntan rúbọ, kò yàtọ̀ sí ẹni tí ó lọ́ ajá lọ́rùn pa. Ati ẹni tí ó fi ọkà rúbọ, ati ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ, bákan náà ni wọ́n rí. Ẹni tí ó fi turari ṣe ẹbọ ìrántí, kò sì yàtọ̀ sí ẹni tí ó súre níwájú oriṣa. Wọ́n ti yan ọ̀nà tí ó wù wọ́n, wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn sin ohun ìríra wọn.