Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 4:3 - Yoruba Bible

3 Kí o pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n gbé òkúta mejila láàrin odò Jọdani yìí, lọ́gangan ibi tí àwọn alufaa dúró sí, kí wọ́n gbé wọn lọ́wọ́ bí ẹ ti ń lọ, kí ẹ sì kó wọn jọ sí ibi tí ẹ óo sùn lálẹ́ òní.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ki ẹnyin si paṣẹ fun wọn pe. Ẹ gbé okuta mejila lati ihin lọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa gbé duro ṣinṣin nì, ki ẹnyin ki o si rù wọn kọja pẹlu nyin, ẹ si fi wọn si ibùsun, ni ibi ti ẹnyin o sùn li alẹ yi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 kí o sì pàṣẹ fún wọn pé Ẹ gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani ní ibi tí àwọn àlùfáà dúró sí, kí ẹ sì rù wọn kọjá, kí ẹ sì gbé wọn sí ibi tí ẹ̀yin yóò sùn ní alẹ́ yìí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 4:3
11 Iomraidhean Croise  

Òkúta tí mo sì gbé nàró bí ọ̀wọ̀n yìí yóo di ilé Ọlọrun, n óo sì fún ìwọ Ọlọrun ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí o bá fún mi.”


Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀,


OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀, ìtẹ́ rẹ̀ wà lọ́run; OLUWA ń kíyèsí àwọn ọmọ eniyan, ó sì ń yẹ̀ wọ́n wò.


Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Mò ń sọ fun yín pé, bí àwọn wọnyi bá dákẹ́, àwọn òkúta yóo kígbe sókè.”


ó bá wí fún gbogbo wọn pé, “Ẹ wo òkúta yìí, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrin wa, nítorí pé ó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ fún wa, nítorí náà, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín, kí ẹ má baà hùwà aiṣododo sí Ọlọrun yín.”


Nígbà tí ẹsẹ̀ àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé bá kan odò Jọdani, odò náà yóo dúró; kò ní ṣàn mọ́, gbogbo omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè yóo sì wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá.”


Joṣua bá pe àwọn ọkunrin mejila tí ó ti yàn tẹ́lẹ̀ ninu àwọn ọmọ Israẹli, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan;


Àwọn ọkunrin náà ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Joṣua pa fún wọn. Wọ́n gbé òkúta mejila láti inú odò Jọdani, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà tí ó wà ninu àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Joṣua. Wọ́n gbé wọn lọ́wọ́ lọ sí ibi tí wọ́n sùn ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì tò wọ́n jọ sibẹ.


Samuẹli gbé òkúta kan, ó rì í mọ́lẹ̀ láàrin Misipa ati Ṣeni, ó sì sọ ibẹ̀ ni Ebeneseri, ó ní, “OLUWA ràn wá lọ́wọ́ títí dé ìhín yìí.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan