Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 4:12 - Yoruba Bible

12 Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ati ìdajì ẹ̀yà Manase náà gòkè odò pẹlu ihamọra ogun níwájú àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, si rekọja ni ihamọra niwaju awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi Mose ti sọ fun wọn:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Àwọn ọkùnrin Reubeni, Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase náà sì rékọjá ní ìhámọ́ra ogun níwájú àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 4:12
9 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn Ọlọrun mú kí wọ́n gba ọ̀nà aṣálẹ̀, ní agbègbè Òkun Pupa, àwọn eniyan Israẹli sì jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu ìmúrasílẹ̀ ogun.


Ninu ẹ̀yà Gadi, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé


Ṣugbọn àwa tìkarawa yóo di ihamọra ogun wa, a óo sì ṣáájú ogun fún àwọn yòókù títí wọn yóo fi gba ilẹ̀ ìní tiwọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ wa yóo máa gbé ninu ìlú olódi níhìn-ín kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà má baà yọ wọ́n lẹ́nu.


“Mo pàṣẹ fun yín nígbà náà, mo ní, ‘OLUWA Ọlọrun yín ti fi ilẹ̀ yìí fun yín bíi ohun ìní; gbogbo àwọn akọni ninu àwọn ọkunrin yín yóo kọjá lọ pẹlu ihamọra ogun ṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli, arakunrin yín.


Ibi tí ó dára jùlọ ninu ilẹ̀ náà ni wọ́n mú fún ara wọn, nítorí pé ibẹ̀ ni ìpín olórí ogun wà, ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn eniyan náà, àtòun, àtàwọn eniyan náà sì ń pa àṣẹ OLUWA mọ́, wọn sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo.”


Àwọn aya yín, àwọn ọmọ yín kéékèèké, ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín ni yóo kù lẹ́yìn lórí ilẹ̀ tí Mose fun yín ní òdìkejì odò Jọdani; ṣugbọn gbogbo àwọn akọni láàrin yín yóo rékọjá sí òdìkejì odò náà pẹlu ihamọra ogun níwájú àwọn arakunrin yín, wọn yóo máa ràn wọ́n lọ́wọ́


Aré ni àwọn eniyan náà sá gun òkè odò Jọdani. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn ti gun òkè odò tan, àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gòkè odò tẹ̀lé wọn, wọ́n sì rékọjá lọ siwaju wọn.


Nǹkan bíi ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọkunrin tí wọ́n ti múra ogun, ni wọ́n rékọjá níwájú OLUWA lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan