Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 3:7 - Yoruba Bible

7 OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Lónìí ni n óo bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọ ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè mọ̀ pé bí mo ti wà pẹlu Mose, bẹ́ẹ̀ ni n óo wà pẹlu rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi gbé ọ ga li oju gbogbo Israeli, ki nwọn ki o le mọ̀ pe, gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o wà pẹlu rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Israẹli, kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 3:7
13 Iomraidhean Croise  

OLUWA gbé Solomoni ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì fún un ní ọlá ju gbogbo àwọn ọba tí wọ́n ti jẹ ṣáájú rẹ̀ ní Israẹli.


Solomoni, ọmọ Dafidi, fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, OLUWA Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀, ó sì sọ ọ́ di ẹni ńlá.


Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi gbé e ga, tí o sì fi ń náání rẹ̀;


O ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó gbé mi ró, ìrànlọ́wọ́ rẹ sì ni ó sọ mí di ẹni ńlá.


Lẹ́yìn tí Jesu ti sọ ọ̀rọ̀ wọnyi tán, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó ní, “Baba, àkókò náà dé! Jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára Ọmọ, kí ògo Ọmọ náà lè hàn lára rẹ.


gẹ́gẹ́ bí igbẹkẹle ati ìrètí mi pé n kò ní rí ohun ìtìjú kan. Ṣugbọn bí mo ti máa ń gbé Kristi ga ninu ara mi pẹlu ìgboyà nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ gan-an náà ni n óo tún máa gbé e ga nisinsinyii ìbáà jẹ́ pé mo wà láàyè tabi pé mo kú.


Bí a ti gbọ́ ti Mose, bẹ́ẹ̀ ni a óo máa gbọ́ tìrẹ náà. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣá ti wà pẹlu rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹlu Mose.


Kò ní sí ẹni tí yóo lè borí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Bí mo ti wà pẹlu Mose ni n óo wà pẹlu rẹ. N kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lae.


Ranti pé mo ti pàṣẹ fún ọ pé kí o múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn rẹ, nítorí pé èmi, OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ níbikíbi tí o bá ń lọ.”


Joṣua bá sọ fún àwọn alufaa pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu náà kí ẹ sì máa lọ níwájú àwọn eniyan yìí.” Wọ́n bá gbé Àpótí Majẹmu náà, wọ́n sì ń lọ níwájú wọn.


Pàṣẹ fún àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu náà pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí odò Jọdani, ẹ wọ inú odò lọ, kí ẹ sì dúró níbẹ̀.’ ”


OLUWA gbé Joṣua ga ní ojú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ọjọ́ náà, wọ́n sì bẹ̀rù rẹ̀, bí wọ́n ti bẹ̀rù Mose ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan