Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 3:6 - Yoruba Bible

6 Joṣua bá sọ fún àwọn alufaa pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu náà kí ẹ sì máa lọ níwájú àwọn eniyan yìí.” Wọ́n bá gbé Àpótí Majẹmu náà, wọ́n sì ń lọ níwájú wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Joṣua si wi fun awọn alufa pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki ẹ si kọja siwaju awọn enia. Nwọn si gbé apoti majẹmu na, nwọn si ṣaju awọn enia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Joṣua sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ̀yin, ẹ gbé àpótí ẹ̀rí náà kí ẹ̀yin kí ó sì máa lọ ṣáájú àwọn ènìyàn.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé e sókè, wọ́n sì ń lọ ní iwájú u wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 3:6
11 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn àgbààgbà ti péjọ, àwọn alufaa gbé Àpótí Ẹ̀rí náà.


Nígbà tí àwọn àgbààgbà péjọ tán, àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí náà.


Ọlọrun tíí ṣí ọ̀nà ni yóo ṣáájú wọn; wọn yóo já irin ẹnubodè, wọn yóo sì gba ibẹ̀ jáde. Ọba wọn ni yóo ṣáájú wọn, OLUWA ni yóo sì ṣiwaju gbogbo wọn.


Wọ́n bá gbéra kúrò ní Sinai, òkè OLUWA, wọ́n rìn fún ọjọ́ mẹta. Àpótí Majẹmu OLUWA sì wà níwájú wọn láti bá wọn wá ibi ìsinmi tí wọn yóo pàgọ́ sí.


Nisinsinyii, bí o bá pa àwọn eniyan yìí bí ẹni tí ó pa ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gbọ́ òkìkí rẹ yóo wí pé;


níbi tí Jesu aṣiwaju wa ti wọ̀ lọ, tí ó di olórí alufaa títí lae gẹ́gẹ́ bíi Mẹlikisẹdẹki.


Wọ́n pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Nígbà tí ẹ bá rí i pé, àwọn alufaa, ọmọ Lefi gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ, kí ẹ̀yin náà gbéra, kí ẹ sì tẹ̀lé wọn.


Joṣua sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nítorí pé OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrin yín ní ọ̀la.”


OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Lónìí ni n óo bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọ ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè mọ̀ pé bí mo ti wà pẹlu Mose, bẹ́ẹ̀ ni n óo wà pẹlu rẹ.


Joṣua, ọmọ Nuni, bá pe àwọn alufaa, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu, kí meje ninu yín sì mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan