Joṣua 3:3 - Yoruba Bible3 Wọ́n pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Nígbà tí ẹ bá rí i pé, àwọn alufaa, ọmọ Lefi gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ, kí ẹ̀yin náà gbéra, kí ẹ sì tẹ̀lé wọn. Faic an caibideilBibeli Mimọ3 Nwọn si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Nigbati ẹnyin ba ri apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti ẹ ba si ri awọn alufa awọn ọmọ Lefi rù u, nigbana li ẹnyin o ṣí kuro ni ipò nyin, ẹnyin o si ma tọ̀ ọ lẹhin. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní3 Wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé: “Nígbà tí ẹ bá rí àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín, tí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi rù ú, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sí kúrò ní ipò yín, ẹ̀yin yóò sì máa tẹ̀lé e. Faic an caibideil |