Joṣua 3:16 - Yoruba Bible16 omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá ní òkèèrè ní ìlú Adamu tí ó wà lẹ́bàá Saretani. Èyí tí ó ń ṣàn lọ sí Òkun Araba tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀ gé kúrò, ó sì dá dúró. Àwọn eniyan náà rékọjá sí òdìkejì ìlú Jẹriko. Faic an caibideilBibeli Mimọ16 Ni omi ti nti oke ṣàn wá duro, o si ga jìna rére bi òkiti li ọnà ni ilu Adamu, ti o wà lẹba Saretani: eyiti o si ṣàn sodò si ìha okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, a ke wọn kuro patapata: awọn enia si gòke tàra si Jeriko. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní16 omi tí ń ti òkè sàn wá dúró. Ó sì gbá jọ bí òkìtì ní òkèèrè, ní ìlú tí a ń pè ní Adamu, tí ó wà ní tòsí Saretani; nígbà tí omi tí ń sàn lọ sínú Òkun aginjù, (Òkun Iyọ̀) gé kúrò pátápátá. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kọjá sí òdìkejì ní ìdojúkọ Jeriko. Faic an caibideil |
“Kí ló dé tí mo wá àwọn eniyan mi tí n kò rí ẹnìkan; mo pè, ẹnikẹ́ni kò dá mi lóhùn? Ṣé n kò lágbára tó láti rà wọ́n pada ni; àbí n kò lágbára láti gba ni là? Wò ó! Ìbáwí lásán ni mo fi gbẹ́ omi òkun, tí mo sì fi sọ odò tí ń ṣàn di aṣálẹ̀, omi wọn gbẹ, òùngbẹ gbẹ àwọn ẹja inú wọn pa, wọ́n kú, wọ́n sì ń rùn.